Liz Benson
Elizabeth Benson (tí a bí ní Oṣù Kẹẹ̀rin Ọjọ́ 5 Ọdún 1966) jẹ́ òṣèré ará orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ó sì tún jẹ́ onínúrere ẹ̀dá.[1]
Elizabeth Benson | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Elizabeth Benson 5 Oṣù Kẹrin 1966 |
Orílẹ̀-èdè | Naijiria |
Iṣẹ́ | Osere itage |
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ rẹ̀
àtúnṣeBenson bẹ̀rẹ iṣẹ́ òṣèré ṣíṣe nígbàtí ó wà lọ́mọdé lọ́mọ ọdún márùn-ún.[2][3][4]
Iṣẹ́-ìṣe rẹ̀
àtúnṣeÀṣeyọrí rẹ̀ àti fífi iṣẹ́ fiimu sílẹ̀
àtúnṣeBenson di gbajúmọ̀ òṣèré nígbàtí ó ṣe ìfihàn nínu Fortunes, eré tẹlif́iṣọ̀nù kan tí àgbéjáde rẹ̀ wáyé ní ọdún 1993. Benson kó ipa ti Ìyáàfin Agnes Johnson nínu eré náà, èyítí ó wáyé fún bi ọdún méjì lóri ìkànni Nigerian Television Authority. Ní ọdún 1994, ipa rẹ̀ nínu Glamour Girls, sinimá àgbéléwò aláṣeyọrí kan tí ó dá lóri panṣágà jẹ́ ókùnfà ìyípadà tó wáyé nínu ayé rẹ̀. Fiimu náà sọ́ di òlókìkí ó sì fa kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olólùfẹ́ fiimu Nàìjíríà fẹ́ràn rẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ri bí ọ̀kan nínu àwọn ìyáàfin àkọ́kọ́ ti Nollywood. Ní ìyàlẹ́nu, ní kété tí iyì rẹ̀ bíi asíwájú òṣèré bẹ̀rẹ̀ sí lékún pàápàá ju bí a ti ṣe lérò lọ, lójijì náà ni Benson fi iṣẹ́ òṣèré sílẹ̀ ní ọdún 1996.
Ìpadàbọ̀ rẹ̀ sí Nollywood
àtúnṣeLátìgbà tí ó ti padà sí Nollywood, a gbọ́ pé ó ti di àtúnbí onígbàgbọ́ tó sì n ṣe wàásù ìhìnrere lemọ́lemọ́.[5][6][7] Nínu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan, ó ṣàlàyé pé òun yóò ṣiṣẹ́ nìkan nínu àwọn fiimu tí ó gbàgbọ́ wípé ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́ rẹ̀.
Ìgbé ayé rẹ
àtúnṣeBenson pàdánù ọkọ àkọ́kọ́ rẹ̀ (Samuel Gabriel Etim) ní àkókò tí ó wà ní àárín àwọn ọdún 20 rẹ̀. Ó ròyìn wípé ìwa ọkọ òun jẹ́ kí òún ní ànfàní láti le tẹ̀síwájú pẹ̀lu mímójútó àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́hìn pípàdánù náà.
Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀
àtúnṣeNínu àwọn ipa rẹ̀ tí ó gbajúmọ̀ jùlọ ni ipa rẹ̀ bi Titubi nínu eré Fẹ́mi Osofisan kan, Moróuntódùn àti Ìyáàfin Agnes Johnson nínu Fortunes, eré tẹlif́iṣọ̀nù kan tí ó wáyé fún bi ọdún méjì lórí ìkànni tẹlif́iṣọ̀nù ti Nàìjíríà (NTA). Ó kópa nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré àgbéléwò Nollywood bíi Evil Men 1 and 2, Shame, Conspiracy, Izaga, Burden, Stolen Child, Faces, Dead End, Tycoon, Glamour Girls, Body of Vengeance àti ogúnlọ́gọ́ àwọn fiimu míràn.
- Lotanna (2017)
- Children of Mud (2017)
- Lizard Life (2017)
- Hilarious Hilary (2015)
- Dearest Mummy (2015)
- Dry (2014)
- Toko taya (2007)
- Political Control (2006)
- Political Control 2 (2006)
- Political Control 3 (2006)
- Bridge-Stone (2005)
- Bridge-Stone 2 (2005)
- Crazy Passion (2005)
- Crazy Passion 2(2005)
- Day of Atonement (2005)
- Now & Forever(2005)
- Now & Forever 2 (2005)
- Squad Twenty-Three (2005)
- Squad Twenty-Three 2 (2005)
- Women in Power (2005)
- Women in Power 2 (2005)
- Inheritance (2004)
- Melody of Life (2004)
- Red Hot (2004)
- Turn Table (2004)
- Turn Table 2 (2004)
- World Apart (2004)
- World Apart 2 (2004)
- Èèkù-idà (2002)
- Èèkù-idà 2 (2002)
- Wisdom and Riches (2002)
- Wisdom and Riches 2 (2002)
- Dapo Junior (2000) .... Ronke
- Chain Reaction (1999)
- Diamond Ring (1998)
- Diamond Ring 2 (1998)
- Scores to Settle (1998)
- Witches (1998)
- Back to Life (1997)
- True Confession (1995)
- Glamour Girls (1994)
- Silenced (????)
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Liz Benson makes a comeback". The Nation. http://thenationonlineng.net/new/liz-benson-makes-a-comeback/. Retrieved 14 March 2015.
- ↑ "Liz Benson, back with a bang!".
- ↑ "Check out Liz Benson, Frederick Leonard, Mimi Orijekwe in upcoming series". Pulse Nigeria. Chidumga Izuzu. Retrieved 21 May 2015.
- ↑ "Liz Benson’s Daughter, Lilian’s Pre Wedding Photos Are So Adorable- See Photos" (in en-GB). Koko Level's Blog. 30 March 2017. http://kokolevel.com/2017/03/liz-bensons-daughter-lilians-pre-wedding-photos-adorable-see-photos/.
- ↑ https://www.pulse.ng/entertainment/celebrities/womancrushwednesday-liz-benson-back-with-a-bang/n9s07mf
- ↑ "I will be damned if I don’t speak out — Liz Benson-Ameye".
- ↑ "Liz Benson returns".
Àwọn ìtakùn Ìjásóde
àtúnṣe- Liz Benson on her new life at 40 Archived 3 March 2016 at the Wayback Machine.
- Liz Benson's Profile on Fimvillage