Lola Ogunnaike
It has been suggested that this article be merged with Àdàkọ:Pagelist. (Discuss) |
Lola Ogunnaike | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 13 Oṣù Kẹ̀sán 1975 New York City |
Orílẹ̀-èdè | American |
Iléẹ̀kọ́ gíga | New York University University of Virginia |
Iṣẹ́ | Journalist |
Employer | Arise News |
Olólùfẹ́ | Deen Solebo |
Àwọn ọmọ | 1 |
Lọlá Ògúnnáìkè jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó tún jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà (American) tí ó jẹ́ amúlùúdùn àti oníròyìn ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà.
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí Lọlá ní ojo ketala osu kesan odun 1975 (September 13, 1975) ní ilu New York City amo awon obi re mejeji je omo orile ede Naijiria. O jade nile eko J.E.B. Stuart High School ni Fairfax, ilu Virginia. O gba oyeko eko-keji ninu ise iroyin ni ile-eko agba ti New York University , nigba ti oye o ti koko gba oye imo akoko ninu imo Litireso Geesi (English literature) nile eko agba University of Virginia.
Ìgbòkè-gbodò iṣé rẹ̀
àtúnṣeÒgúnnáìkè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí oníròyìn ní ọdún1999 nípa ṣíṣe ìròyìn amúlùúdùn àti àwọn àṣà míràn tó bá jẹ yọ. Bákan náà ni ó ń jábọ̀ ìròyìn fún ile iṣẹ́ ìròyìn ti New York Times tí ó sì jẹ́ ọ̀gá ní ẹ̀ka ìròyìn amúlùúdùn tí ó ń ṣe pẹ̀lú bí ó ṣe dajú kọ àwọn olórin ilè Amẹ́ríkà ọlọ́kan ò jọ̀kan bíi: Jennifer Lopez, Ozwald Boateng, Oprah Winfrey, tí ó sì ń kọ àwọn ọ̀rọ̀ kóríyá nípa "Àṣà àti Ìsinmi" lápá kan inú ìwé ìròyìn náà. Bákan náà ló tún jẹ́ akọ̀ròyìn fún ìwé ìròyìn "Vibe magazine", ní èyí tí ó fi ń dá sí àwọn ìròyìn olóṣooṣù nípa orin àti àwọn ìròyìn tó jẹ mọ́ tàwọn ọ̀kọrin gbogbo. Ó sì tún kọ ìròyìn fún ìwé ìròyìn bíi: Rolling Stone, New York, Glamour, Details (magazine), Nylon, "New York Observer" àti "V Magazine". Ó sì tún wà lára àwọn ikọ̀ tí ó fọ̀rọ̀ wá aya olórí orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà tẹ́lè ̣rí lẹ́nu wò ìyẹn: Michelle Obama lórí àbẹ̀wò rẹ̀ sí orílẹ̀ èdè South Africa. Lọlá tún jẹ́ ajábọ̀ ìròyìn fún "New York Daily News","NOW," "Rush, lórí ìròyin pàjáwìrì tí ó jẹ mọ́ ti amúlùud́ùn àti "Molloy" bákan náà ni ó tún jẹ́ ajábọ̀ ìròyìn fún ilé iṣẹ́ agbóhùn sáfẹ́fẹ́ ti CNN’s “American Morning"[1] níbi tí ó ti ṣiṣẹ́ láti ọdún 2007 tí tí di 2009.[2][3]
Lọlá ti hàn lórí àwọn ètò ọlọ́kan ò jọ̀kan orí ẹrọ amóhùn-máwòrán bíi: NBC’s today Show, MTV àti VH1. Wọ́n kàá ní oṣù karùn ún ọdún 2007 (May 2007) mọ́ àwọn obìnrin aláwọ̀ dúdú tí ó nípa jùlọ ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà (Ebony’s ‘150 Most Influential Blacks in America”). Lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyìí, òun ni ó dá Arise Entertainment 360 sile
ìgbésí ayé rẹ̀
àtúnṣeÒun ni ìyàwó fún Deen Ṣólebọ, tí wọ́n sì bí ọmọ ọkùnrin kan ṣoṣo.[4][5]
Àwọn ìtọ́ka sí
àtúnṣe- ↑ Ann Powers (2010). Best Music Writing. Da Capo Press. ISBN 978-0-306-8192-54. https://books.google.com.ng/books?id=CskBAwAAQBAJ&pg=PA326&dq=lola+ogunnaike+at+CNN&hl=en&sa=X&ved=0CDIQ6AEwBWoVChMI3saW68D3xwIVITrbCh1KSA-j.
- ↑ Inc. Real Times Media; Charles Rangel (2009). Who's Who in Black New York City: The Inaugural Edition. Who's Who Publishing Company (Northwestern University). ISBN 978-1-933-8795-50. https://books.google.com.ng/books?id=BN8iAQAAMAAJ&q=lola+ogunnaike+at+new+york+times&dq=lola+ogunnaike+at+new+york+times&hl=en&sa=X&ved=0CD0Q6AEwBzgKahUKEwj5luqpv_fHAhUDGNsKHWVGCtM.
- ↑ Ronald H. Bayor. Multicultural America: An Encyclopedia of the Newest Americans. ABC-CLIO, 2011. p. 1641. ISBN 9780313357879. https://books.google.com.ng/books?id=YN9jC2_7UHYC&pg=PA1641&dq=lola+ogunnaike+at+the+new+york+times&hl=en&sa=X&ved=0CEsQ6AEwCWoVChMI_sW0lL_3xwIVZQvbCh0zFQ6d#v=onepage&q=lola%20ogunnaike%20at%20the%20new%20york%20times&f=false.
- ↑ "It’s a Boy! Lola Ogunnaike Shares a Picture of Her Bundle of Joy, Elias OluwaDairo Solebo". Bella Naija. December 23, 2014. http://www.bellanaija.com/2014/12/23/its-a-boy-lola-ogunnaike-shares-a-picture-of-her-bundle-of-joy-elias-oluwadairo-solebo/. Retrieved September 15, 2015.
- ↑ "Lola Ogunnaike Speaks on Young Africa: Nigerian-American journalist will travel to Africa with first lady Michelle Obama and host a BET special.". BET. Retrieved September 15, 2015.