Lucy Jumeyi Ogbadu (ọjọ́ ìbí rẹ̀ ni ọjọ́ karúndílógbọ̀n oṣù kẹsàn ọdún 1953) jẹ́ ọmọ orílè-èdè Nàìjíríà tí ó jẹ́ onímọ̀ nípa àwọn kòkòrò aifojuri, pàápàá jùlọ, àwọn tí ó ń fa àìsàn, ósì ti ṣíṣe gẹ́gẹ́ bí Adarí àgbà àti Olùdásílẹ̀ ilé iṣé National Biotechnology Development Agency (NABDA), ilé iṣé tí ó ń ṣiṣẹ́ ìwàádìí lórí ìmọ sáyẹnsì lábẹ́ Àjọ tí ó mójú tó Ìmọ Sáyẹnsì àti Tẹkinọ́lọ́jì ní orílé èdè Nàìjíríà (Nigerian Ministry of Science & Technology) títí di ìparí Ọjọ́ tí ó dá ní ọdún 2018.[1]

Professor Ogbadu

Iṣé àtúnṣe

Kí ó tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ rẹ gẹ́gẹ́ bí Adarí àgbà àti Olùdarí NABDA ni oṣù kọkànlá ní ọdún 2013, Ogbadu ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Olùkọ ní Fásiti tí ó tí kàwé Ahmadu Bello University ní ìpínlè Sáríà fún ògún odún, lẹyìn èyí tí o tún ṣiṣẹ́ Olùkọ ní Fásiti tí ó wà ní Benue, ìpínlè Makurdi fún ọdún mẹ́fà.[2] ní ọdún 2002, o jẹ́ ipò Adarí lori iṣẹ́ ìwádìí àti ìdàgbàsókè ni NABDA, lẹyìn na ní o sìse láti ọdún 2004 Títí dé 2005 gẹ́gẹ́ bí Adarí àgbà ní Bioentrepreneurship. Ogbadu na ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi Adarí fún osù ránpẹ́ ni NABDA fún osù mẹ́ta ni ọdún 2005, lẹyìn tí ó di olórí ẹ̀ka fún food and industrial Biotechnology ni NABDA láti ọdún 2005 dé 2011. Bákan náà ní ó jẹ́ Adarí àgbà fún ìwàádìí láti 2011 dé 2013, nígbà náà ni ó tó dé ipo to ó wà lónì.[3]

Ogbadu ni ó kọ́kọ́ bẹ́rẹ́ gbígbé "Temporary Immersion Bioreactor System" láti AZUTECNIA ní Cuba wásí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà fún mass production àwọn elite plantlets.Àdàkọ:Clarify. Bákan náà ní ó tún dèrò ìforúkọsílẹ̀ ti àkọsílẹ òye lórí ìṣelọ́pọ̀ àjẹsára láàrin Finlay tí ilé Kúbà àti orilẹ èdè Nàìjíríà (FMST, Federal University of Technology, Minna àti [[Centers for Disease Control and Prevention|CDC ti wọn jọ́ ń ṣiṣẹ pọ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2013.Àdàkọ:Clarify

Nígbà àkókò iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí adelé Olùdarí Gbogbogbò, Ogbadu dá àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Nàìjíríà padà sípò ní International Centre for Genetic Engineering and Biotechnology. Àwọn iṣẹ́ àkànṣe biotechnology ní ìpilẹ́ṣẹ́ nípasẹ̀ ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹlú àjọ Oúnjẹ àti Ọ̀gbìn tí Àjọ Àgbáyé lábẹ́ ìfọwọ́sowọ́pọ̀ South South ní àsìkò yìí.Àdàkọ:Clarify

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2014 nígbà àìsàn Ebola tán kàà ní apá ìwọòrùn, èyí ló mú ki NABDA lábẹ́ ìtọ́sọ́nà rẹ̀ ṣẹ àgbékalẹ̀ àwọn ìwádìí àti àwọn alákóso fún iṣẹ́ ìwádìí Aisan Ebola. Àwọn ohùn èlò náà ní agbára láti wá àìsàn yìí láàrin wákàtí mérìnlélógún tí wọn tí kò ààrùn yíì, pàápàá ṣáájú kí àwọn àmì àìsàn tó bẹ́rẹ́ sí ní hàn, láti lè dẹ́kun ìtànkálẹ̀ àrùn náà. Èyí wá sí ìmúṣẹ nípa àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ilé iṣẹ Biotechnology Bioneer ni orílẹ̀-èdè South Korea.

Lábẹ́ ọdún méjì tí ó ṣíṣe adarí gẹ́gẹ́ bí Olùdarí Gbogbogbò, Ó ṣàṣeyọrí ní títarí àti gbígbé ìwé-àṣẹ Biosafety tí orílé èdè Naijiria, èyítí ó tí wá ní ìpatì láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2002, ninu òfin. Bákan náà, àbádòfin Biotechnology tí gba ìfọwọ́sí Federal Executive Council láàrin àsìkò kan náà, ó sì ti wà ṣáájú Àpéjọ orilẹ-ède. Ètò ìlànà ìmọràn fún ọdún márún tún ti gbèrò sókè ní ìgbà àkọ́kọ́ tí ó sì wà ní ìmúṣẹ lọ́wọ́lọ́wọ́.

Ìwé tí o ti wa ni àtẹ̀jáde àtúnṣe

Ogbadu ti tẹ ogójì ìwé tí àwọn kan je lára iṣẹ ìwàádìí rẹ̀ ti àwọn mìíràn sí jẹ́ ìwé àkọsílẹ, àwọn kàn sí jẹ́ àwọn ìwé àkọsílẹ òkèrè, nígbà tí ìyókù jẹ́ ìwé àkọsílẹ tí ilé wà níbí sùgbọ́n tí o wà ní nípò tí ó ga. Ogbadu tí dásí àwọn àgbàlá inú ìwé yágbó yájù Elsevier lórí Food Microbiology. Ó sí tí kọ́we tí ó ṣọ́rọ́ lórí ẹ ni Seminar tí ó ń lọ bí méjìlélógún àti àwọn bẹ́bà lọ́lọ́kan òjòkan ní àwọn ìpérò sáyẹns.[citation needed]

Àwọn Ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. "Passage of Biotech Law will boost scientific inventions in Nigeria, say Ogbadu, Ekong". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2015-05-28. Retrieved 2022-08-10. 
  2. "Professor Lucy Jumeyi Ogbadu". JR Biotek Foundation (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2019-05-08. Retrieved 2019-05-08. 
  3. Whistler, The (2017-08-01). "NABDA: Professor Ogbadu’s Landmarks On Biotech Development". The Whistler Newspaper (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-08-10. 

External links àtúnṣe

Àdàkọ:Authority control