Lula Ali Ismail (tí wọ́n bí ní ọdún 1978) jẹ́ olùdarí eré àti ònkọ̀tàn ọmọ orílẹ̀-èdè Djibouti àti Canada. Òun ni obìnrin àkọ́kọ́ láti gbé eré jáde lórílẹ̀-èdè Djibouti.[1] Ó ṣe adarí eré oníṣókí tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Laan ní ọdún 2011.[2] Wọ́n wo fíìmù náà níbi ayẹyẹ Vues d'Afrique Festival tí ó wáyé ní ìlú Montreal ní ọdún 2012, àti ní ọdún 2103 níbi ayẹye FESPACO. Ní ọdún 2014, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ lóri fíìmù gígùn kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Dhalinyaro,[3] èyí tí òun pẹ̀lú Alexandra Ramniceanu àti Marc Wels dì jọ kọ ìtàn rẹ̀.[4] Wọ́n kọ́kọ́ gbé eré náà jáde ní Oṣù Keèje Ọdún 2017.[5]

Lula Ali Ismaïl
Ọjọ́ìbí1978
Djibouti
Iṣẹ́
  • Director
  • writer
  • actress
Ìgbà iṣẹ́2011–present

Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀

àtúnṣe
  • Laan, 2011
  • Dhalinyaro 2017

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Lula Ali Ismaïl, la First Lady du cinéma djiboutien. Jeune Afrique
  2. Beti Ellerson, "African Women of the Screen as Cultural Producers: An Overview by Country", "Black Camera", Vol. 10, No. 1 (Fall 2018), pp. 245–87.
  3. DHALINYARO: A feature film made-in-Djibouti Archived 2019-07-16 at the Wayback Machine., La Nation, 18 August 2016.
  4. Clarisse Juompan-Yakam, Lula Ali Ismaïl, la First Lady du cinéma djiboutien, Jeune Afrique, 24 January 2014.
  5. Cinéma : Avant-première du film "Dhalinyaro" Archived 2019-07-16 at the Wayback Machine., The Nation, 30 July 2017.