M'Bala Nzola (ti a bi ni ọjọ kejidinlogun Oṣu Kẹjọ ọdun 1996) jẹ alamọdaju agbabọọlu ti orilẹ-ede Angola ti o ṣere bi agbabọọlu fun Olugba Serie A Spezia ati ẹgbẹ orilẹ-ede Angola .

M'Bala Nzola

Ise Egbe Agbabọọlu

àtúnṣe

Ni 28 Oṣu Kini 2015, Nzola gba bọọlu akọbgba ti ọjọgbọn rẹ pẹlu Académica de Coimbra ni 2014-15 Taça da Liga ninu ifẹsẹwọnsẹ lodi si FC Porto, nibiti bi ti je aropo ninu ti won ti pàdánù si 4-1. [1]

Ni ọjọ keje oṣu kejo ọdun 2016, o darapọ mọ egbe agbabọọlu Lega Pro kan Virtus Francavilla Calcio . [2]

Ni ọjọ keje oṣu kejo odun 2017, lẹhin ti o ṣe iranlọwọ fun Virtus Francavilla Calcio de Lega Pro igbega play-offs, Nzola fowo si adehun ọdun mẹrin pẹlu Carpi FC 1909 . [3]

Ni ọjọ kerindinlogun Oṣu Kẹjọ 2018, o darapọ mọ egbe agbabọọlu Serie C Trapani lawin. Trapani ṣe adehun lati ra lati ọdọ Carpi ni opin akoko ni awin ti Trapani na ni igbega si Serie B. [4] Ni ọjọ keedogun Oṣu kẹfa o gba goolu akọkọ ninu ifẹsẹwọnsẹ Trapani ti na Piacenza, ati lẹhin iyẹn ni Trapani ni igbega si Serie B lẹhin ọdun meji ni Serie C.

Ni ọjọ ketala Oṣu Kini Ọdun 2020, o darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Serie B Spezia ni awin pẹlu aṣayan lati ra.

Ni ọjọ keje Oṣu Kẹwa Ọdun 2020, Nzola fowo si iwe adehun ọdun mẹta pẹlu Spezia.

Ti a bi ni orilẹ-ede Angola, ṣugbọn o dagba ni orilẹ-ede Faranse, Nzola le ṣe aṣoju awọn orilẹ-ede mejeeji ni ipele kariaye.

Ni oṣu Kẹta ọdun 2021, awọn oṣu diẹ lẹhin ti o ṣalaye ifẹ rẹ lati ṣoju orilẹ-ede Angola, o gba ipe akọkọ rẹ si ẹgbẹ agbabọọlu orilẹ-ede. Awọn ọjọ diẹ lẹhin, ni ọjọ karundinlgbon Oṣu Kẹta Ọdun 2021, o ṣe akọse ise rẹ fun Palancas Negras ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Gambia, ni idije ti o yẹ fun Ife orilẹ-ede Afirika .

Ti a bi ni Cabinda, ara Angolan exclave, Nzola ṣilọ si orilẹ-ede Faranse nigha to je ọmọde.

Awọn iṣiro iṣẹ

àtúnṣe
  1. "Porto 4-1 Académica". ZeroZero. 16 September 2015. https://www.thefinalball.com/jogo.php?id=4259010. 
  2. "M’Bala Nzola è un nuovo giocatore della Virtus Francavilla Calcio" (in it). Virtus Francavilla Calcio. 7 August 2016. https://www.virtusfrancavillacalcio.it/2016/08/07/mbala-nzola-e-un-nuovo-giocatore-della-virtus-francavilla-calcio/. Retrieved 18 September 2018. 
  3. "Mercato: Nzola è ufficialmente biancorosso" (in it). Carpi F.C. 1909. 7 August 2017. Archived from the original on 30 November 2020. https://web.archive.org/web/20201130100547/https://www.carpifc.com/news-prima-squadra/mercato-nzola-e-ufficialmente-biancorosso/. Retrieved 9 August 2017. 
  4. Empty citation (help)