Bardo National Museum (Lárúbáwá: المتحف الوطني بباردو‎; Faransé: Musée national du Bardo) jẹ́ musíọ́mù kan ní Tunis, Tunisia, tí ó wà ní ìlú Le Bardo.

Bardo National Museum
Ìyàrá tí wọ́n ń pè ní Virgil.
Building
LocationLe Bardo, Tunis, Tunisia

Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn musíọ́mù tí ó ṣe pàtàkì jù ní orílẹ̀ èdè náà àti musíọ́mù kejì lẹ́yìn Egyptian Museum of Cairo tí ó ní àwọn ǹkan nínú jùlọ ní ilẹ̀ Áfríkà.[1] Ó so nípa Ìtàn ilẹ̀ Tùnísíà láti ọdún mọ́dún nípasẹ̀ àwọn ohun ayé ọjọ́ ohùn tí wọ́n wú nínú ilẹ̀.

Musíọ́mù náà wà ní ààfin beylical láti ọdún 1888, ó jẹ́ ibi tí ọ̀pọ̀lopọ̀ ti ń fi iṣẹ́ wọn hàn. Orúkọ tí wọ́n kọ́kọ́ fun ni Alaoui Museum (Lárúbáwá: المتحف العلوي‎), wọ́n fun lórúkọ yìí tẹ́lé ọba tí ó jẹ́ nígbà náà, orúkọ rẹ̀ lẹ́yìn òmìnira orílẹ̀-èdè Tunisia ni Bardo Museum.

Wọ́n ni àwọn ère láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè níbẹ̀, àwọn orílẹ̀ èdè bi Róòmù, Tunisia àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ó ní ẹ̀ka Islam tí ó jẹ́ ilé fún iṣẹ́ Blue Qur'an of Kairouan, àti àkójọ ceramic láti Maghreb àti Anatolia.

Ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kẹta ọdún 2015, ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí kan ya wọ musíọ́mù náà, wọ́n sì kó ọ̀pọ̀ àlejò musíọ́mù náà ní ìgbèkùn, wọ́n pa ènìyàn méjìlélógún ní ọjọ́ náà. Àwọn ISIS padà ní pé iṣẹ́ owó àwọn ni.

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Zaiane, Selma (2008). "Le musée national du Bardo en métamorphose. Pour une nouvelle image du tourisme culturel tunisien et de nouveaux visiteurs". Téoros 69: 2.