Mande
Ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà ni àwọn ènìyàn tí ó ń sọ èdè yìí Sodo sí jùlọ. Àwọn ìhú tí a sì ti rí àwọn tí èdè wọn pẹ̀ka láti ara orí èdè yìí ni Mali, Cote d’Ivoire, Sierra Leone, Liberia, Burkina Faso, Senegal, Gambia, Guinea Bissau, Mauritania, Banin, Ghana, Togo ati Nigeria (Dwyer 1989; Kastenholz 1991/2). Ó tó ènìyàn bíi mílíọ̀nù mẹ́wàá sí méjìlá tí wọ́n ń sọ ọ́. Ẹ yẹ àtẹ ìsọ̀rí yìí wò.
Àpapọ̀ iye oníbùgbé |
---|
27 millions |
Regions with significant populations |
West Africa |
Èdè |
Ẹ̀sìn |
Predominantly Muslim |
Ẹ̀yà abínibí bíbátan |
Bambara, Bissa, Busa, Dan, Dyula, Kpelle, Ligbi, Malinké, Mandinka, Marka, Mende, Soninke, Susu, Vai, Yalunka, many others |
Nínú àtẹ yìíu a rí ‘Proto-Mande’ tí ó pín sí ìwọ̀ oòrùn àti ìlà oòrùn ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀. A wá rí ìwọ̀ oòrùn fúnrarẹ̀ tí ó tún wá pín sí ààrín gbùngbùn tàbí Gúúsù-ìwọ̀ oòrùn àti Àríwá ìwọ̀ oòrùn. Láti ara ààrín gbùngbùn tàbí Gúúsù-ìwọ̀ oòrùn ni a ti rí: Mandaing ati Koranko, Vai àti Kono, Jogo (Ligbi, Nnmu, Atumfuor, Wela) àti Jeri, Sooso àti Yalunka, Kpelle, Loomu, Bandi, Mande ati Loko. Láti ara àríwá-ìwọ̀ oòrùn ni a ti rí Sorogama àti Tieyaxo, Tiema Cewe, hainyaxo, Soninke (Azer), Bobo (Sya), Dzuun (Samogo-Guan) àti Sembia, Jo (Samogo-Don). Ní ìlà Oòrùn a rí : Mano, Dan (Yakuba, Gio) àti Tura (Wen), Guro (Kweni) àti Yanre, Mwa àti Wan (Nwa), Gban àti Beng (Gan). Bákan náà, ni a rí: Bisa, Sane (Samogo-Tongan, Maya) àti San (South Samo, Maka), Busa (Bisa, Boko), Shanga àti Tyenga
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |