Mangbetu

Àwọn ènìyàn yìí wà ní abala àríwá Congo, wọ́n sì tó ọ̀kẹ́ méjì ni iye. Èdè mangbetuti ni wọ́n ń sọ, wọ́n sì múlé gbe àwọn Azande, Mbuti àti Momvu. Ọ́ jọ pé orílẹ̀ èdè Sundan ni wọ́n ti sẹ̀ wá; àgbẹ̀, ọdẹ àti apẹja sì ni wọ́n. Òrìṣà Kilima tàbí Noro ni wọ́n ń bọ gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́dàá, wọn a sì máa bọ Ara náà.