Marcus Mosiah Garvey Jr. ONH (17 August 1887 – 10 June 1940) jẹ́ alákitiyan olóṣèlú, atẹ̀wéjáde, oníròyìn, oníṣòwò, àti ọlógbọ́n-ọ̀rọ̀ ará Jamáíkà. Òhun ló jẹ́ olùdásílẹ̀ àti Ààrẹ-Gbogbogbòò ẹgbẹ́ Universal Negro Improvement Association and African Communities League (UNIA-ACL, tó gbajúmọ̀ bíi UNIA). Ìròayé rẹ̀ sọ ọ́ di aṣeọmọorílẹ̀-èdè aláwọ̀dúdú àti Aṣe Pan-Afrikanisti, àwọn ìròayé rẹ̀ ni a mọ̀ sí Iṣe Garvey.

Marcus Garvey
Fọ́tò Garvey ní ọdún 1924
Ọjọ́ìbí(1887-08-17)17 Oṣù Kẹjọ 1887
Saint Ann's Bay, Jamaica
Aláìsí10 June 1940(1940-06-10) (ọmọ ọdún 52)
West Kensington, London, England, United Kingdom
Iléẹ̀kọ́ gígaBirkbeck, University of London
Iṣẹ́Atẹ̀wéjáde, oníròyìn
Gbajúmọ̀ fúnActivism, black nationalism, Pan-Africanism
Olólùfẹ́
Amy Ashwood
(m. 1919; div. 1922)

Amy Jacques (m. 1922)
Àwọn ọmọ2
Parent(s)Marcus Mosiah Garvey Sr.
Sarah Anne Richards

Wọ́n bí Garvey ní Saint Ann's Bay, Jamáíkà nibi tó ti kọ́ṣẹ́ ìtẹ̀wé nígbà tó wà ní ọ̀dọ́. Ní ilú Kingston, ó darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ kó tó kò lọ sí Costa Rica, Panama, àti England fún ìgbà díẹ̀. Nigbà tó padà sí Jamáíkà, ò dá ẹgbẹ́ UNIA sílẹ̀ ní ọdún 1914. Ní ọdún 1916, ó kó lọ sí Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, níbẹ̀, ó dá ẹ̀ka UNIA sílẹ̀ ní àdúgbò Harlem ní ilú New YorK. Ó tẹnumọ́ ìfọwọ́sọwọ́pọ̀ láàrin àwọn ará Áfríkà àti àwọn ará Áfríkà èyìn odi, ó jà láti fòpin sí ìjọba ìmúnisìn àwọn òyìnbó káàkiri ilẹ̀ Áfríkà àti fún ìṣọ̀kan olóṣèlú gbogbo ìlẹ̀ Áfríkà.Itokasi àtúnṣe