Mariama Sylla

Oludari fiimu Senegal

Mariama Sylla Faye jẹ oludari fiimu Senegalese ati oludasiṣẹ.

Mariama Sylla
Ọjọ́ìbíDakar
Orílẹ̀-èdèSenegalese
Iṣẹ́Film director, film producer

Ìsẹ̀mí rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí Sylla ní ìlú Dakar ó síì jẹ́ àbúrò sí ònkọ̀tàn kan tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Khady Sylla.[1][2] Ìyá rẹ̀ náà ṣiṣẹ́ ní ilé-iṣẹ́ kan tí ó n rí sí sinimá. Sylla ti ní ìfẹ́ sí eré sinimá ṣíṣe láti ìgbà tí ó wà lọ́mọ ọdún méje, nígbà tó jẹ́ wípé wọ́n maá n lọ ilé wọn láti fi ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn fíìmù.[3]

Sylla dá ilé-iṣẹ́ agbéréjáde kan sílẹ̀ ní ọdún 2003, èyítí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Guiss Guiss Communication.[4] Ó ṣe adarí eré oníṣókí kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Dakar Deuk Raw ní ọdún 2008, èyítí ó ṣe àyẹ̀wò ẹ̀yà Lesbous ní ìlú Dakar. Ní ọdún 2010, Sylla darí eré Skirmisher Marc Gueye: My Pen, My Fight.[5]

Sylla àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin Khady dì jọ ṣe olùdarí eré ti ọdún 2014 kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Une simple parole. Ó parí eré náà lẹ́hìn tí Khady ṣaláìsí.[6] Fíìmù náà ṣe àyèwò àṣà ìtàn sísọ ní orílẹ̀-èdè Sẹ́nẹ́gàl, eré náà síì gba àmì-ẹ̀yẹ kan níbi ayẹyẹ Women's International Film and Television Showcase.[7]

Sylla ti ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú òṣìṣẹ́ agbéròyìn kan tí orúkọ rè jẹ́ Modou Mamoune Faye.[8]

Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀

àtúnṣe
  • 2005 : Derrière le silence (director)
  • 2006 : Hors Série (director)
  • 2008 : Dakar Deuk Raw (short film, director)
  • 2010 : Skirmisher Marc Gueye: My Pen, My Fight (director)
  • 2014 : Une simple parole (co-director)

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Mariama Sylla". Festival Scope. Retrieved 16 November 2020. 
  2. "Une Fenêtre ouverte & Le Monologue de la muette". Centre Wallonie-Bruxelles (in French). Archived from the original on 17 November 2020. Retrieved 16 November 2020. 
  3. "Mariama Sylla Faye". Africultures (in French). Retrieved 16 November 2020. 
  4. "Mariama Sylla Faye". Africultures (in French). Retrieved 16 November 2020. 
  5. "Mariama Sylla Faye". Africultures (in French). Retrieved 16 November 2020. 
  6. "Une Fenêtre ouverte & Le Monologue de la muette". Centre Wallonie-Bruxelles (in French). Archived from the original on 17 November 2020. Retrieved 16 November 2020. 
  7. "Mariama Sylla - Khady Sylla The Diversity Award - A Single Word - Senegal". Women's International Film and Television Showcase. Retrieved 16 November 2020. 
  8. "Mariama Sylla Faye". Africultures (in French). Retrieved 16 November 2020. 

Àwọn ìtakùn Ìjásóde

àtúnṣe