Mary Lazarus

òṣèré orí ìtàgé àti o ńṣe fíìmù ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà

Màríà Lásárù (tí a bí ní ọjọ́ karùn ún oṣù karùn ún ọdún 1989)[1] jẹ́ òṣèré àti ò ǹṣe fiimu ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Òun ni ó gba àmì ẹ̀yẹe lórí fiimu àwọn ènìyàn ìlú fún òṣèré tí ó ní ìlérí tí ó dára jùlọ ní ibi ẹ̀buǹ eré ìdárayá ti i àwọn ènìyàn ìlú (City People Entertainment Awards) ti odun 2018[2], wọ́n sì tún yàn án gẹ́gẹ́ bí i òṣèré tí ó dára jùlọ nínú ipa olùdarí ní ọdún kanná àn níbi ayẹyẹ ẹ̀bùn fún àwọn òṣèré Nollywood tí ó dára jùlọ (Best of Nollywood Awards).[3]

Mary Lazarus
Ọjọ́ìbíMary Lazarus
5 Oṣù Kàrún 1989 (1989-05-05) (ọmọ ọdún 35)
Abia State, Nigeria
Orílẹ̀-èdèNigerian
Iléẹ̀kọ́ gígaUniversity of Ibadan
Iṣẹ́
  • Actress
  • Movie producer
Ìgbà iṣẹ́2002–Present

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ àti ẹ̀kọ́

àtúnṣe

Lásárù wá làti Ìpínlẹ Abia ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìpínlẹ Abia wà ní agbègbè gúúsù ìla oorun ti oríl̀ẹ̀-èdè Nàìjíríà níbi tí ó jẹ wípé àwọn ẹ̀yà Ìgbò ni wọ́n wà níbẹ̀. Ukwa tí ó wà ní Ìjọba Ìbílẹ̀ ìla-oorun ní Ìpínlẹ̀ Abia gangan ni Lásárù ti wá. Ìdílé ẹlẹ́ni mẹ́sàn án ni a bí Lásárù sí èyí tí ìyá, bàbá pẹ̀lú àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò rẹ wa. Ó jẹ́ ìbejì nínú ẹbí yi àti wípé òun àti èkejì rẹ, Joseph tí ó jẹ́ ọkùnrin ni wọ́n bí gbẹ̀yìn.[4] Nígbà tí Lásárù ti lọ sí ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti ti girama tí ó sì ti gba ìwé ẹ̀rí moyege ní pàtàkì ti girama (West African Senior School Certificate), ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì ti Ìbàdàn (University of Ibadan) níbi tí ó ti kọ́ ẹ̀kọ́ gba ìwé ẹ̀rí tí ó múnádóko lórí i Àlà-ilẹ̀ (Geography).[5][6]

Iṣẹ́ rẹ

àtúnṣe

Lásárù tí ó jẹ́ olókìkí jùlọ nínú àwọn ipa tí ó ti kó nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn fiimu ti Nollywood, ó ṣe ìṣàfihàn akọ́kọ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí i aláwòṣe ní ọdún 2002 kí ó tó wa darí lọ sí ilé-iṣẹ́ fiimu ti Nàìjíríà ní ọdún 2009 pẹ̀lú fiimu kan tí àkọlé rẹ ń jẹ́ "Waiting Years". Lásárù rí ipa kan kó nínú fiimu yi látipasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ Gbenro Ajibade ẹni tí ó ṣàfihàn rẹ sí John Njamah, ẹni tí í ṣe olúdarí fiimu yi tí ó sì tún wá fún un ní ipa tí yíò kó nígbẹ̀yìn nínú fiimu tí a ti dárúkọ rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Lásárù darí ìṣàfihàn fiimu kan tí àkọlé rẹ ń jẹ́ "Dance To My Beat", èyí tí ó tún gbé jáde ní ọdún 2017.

Lásárù gẹ́gẹ́ bí i aláwòṣe ti fi arahàn nínú oríṣiríṣi àwọn ìkéde ti ilé-iṣẹ́ Airtel àti MTN ti ṣe.

Àwòkọ́ṣe

àtúnṣe

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn oníròyìn ti ìwé ìròyìn Vanguard, Lásárù dárúkọ ọmọtọla Jalade Ekeinde àti Jọkẹ Silva tí wọ́n jẹ́ gbajúgbajà òṣèré Nollywood gẹ́gẹ́ bí i àwọn tí òún ń wò kọ́ ìṣe wọn nínú iṣẹ́ fiimu ní Nàìjíríà. Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò míràn àn pẹ̀lú àwọn oníròyìn ìwé ìròyìn The Punch, Lásárù dárúkọ òṣèré bìnrin ọmọ ilé Amẹ́ríkà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kimberly Elise gẹ́gẹ́ bí i ọ̀kan lára àwọn tí òún fẹ́ràn nítorí àwọn iṣẹ́ rẹ tí ó ti gbòòrò.[7]

Àmì Ẹ̀yẹ àti yíyàn

àtúnṣe
  • Lásárù gba àmì ẹ̀yẹ lórí i fiimu ti àwọn ènìyàn ìlú fún òṣer̀é tí ó ní ìlérí tí ó dára jùlọ èyí tí ó wáyé ní City People Entertainment Award ti ọdún 2018.[8]
  • A yan Lásárù gẹ́gẹ́ bí i òṣèré tí ó dára jùlọ ní ipa ti olùdarí, èyí tí ó wáyé níbi àwọn ẹ̀bùn ẹ̀yẹ ti BON ní ọdún 2018.
  • Wọ́n yan Lásárù níbi ayẹyẹ ti 2020 Africa Magic viewer's choice award gẹ́gẹ́ bí i alátìlẹyìn òṣèré tí ó dára jùlọ lórí oríṣiríṣi ipa kíkó nínú un fiimu tàbí tẹlifísànù fún fiimu ti "Size 12".[9]

Ìgbésí ayé rẹ

àtúnṣe

Lásárù wá láti ìdílé ẹlẹ́ni mẹ́sàn án. Ìbejì ni Lásárù. Òun àti ìkejì rẹ tí ó jẹ́ ọkùnrin ni wọ́n jẹ́ àbígbẹ̀yìn ìya wọn. Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn oníròyìn ti ìwé ìròyìn The Punch, ó ṣàpèjúwe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i ẹnìkan tí ó fẹ́ràn ìgbádùn.

Àwọn àṣàyàn fiimu àti eré oríṣiríṣi lórí tẹlifísànù

àtúnṣe
  • When Life Happens (2020) as Cindy | with Lota Chukwu, Jimmy Odukoya, Wole Ojo
  • My Woman (2019) as Zara | with Seun Akinyele, Ujams C'briel
  • Accidental Affair (2019) as Kristen
  • Clustered Colours (2019)
  • Broken Pieces (2018)
  • Homely: What Men Want (2018) as Keji
  • Dance To My Beat (2017)
  • The Road Not Taken II (2017)
  • Love Lost (2017) as Rena
  • Girls Are Not Smiling(2016)
  • What Makes You Tick (2016) as Ann Okojie
  • Okafor’s Law (2016) as Kamsi
  • Better Than The Beginning (2015)
  • Bad Drop (2015)
  • Losing Control (2015) as Uche
  • Second Chances (2014) as Justina
  • Desperate Housegirls (2013)
  • Waiting Years (2009)

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Izuzu, Chibumga (2016-05-05). "5 Nollywood movies featuring actress". Pulse Nigeria. Retrieved 2020-10-16. 
  2. "Winners Emerge @ 2018 City People Movie Awards". City People Magazine. 2018-09-24. Retrieved 2020-10-16. 
  3. "BON Awards 2018: Mercy Aigbe, Tana Adelana shine at 10th edition". Pulse Nigeria. 2018-12-09. Retrieved 2020-10-16. 
  4. [nigeria.shafaqna.com "Nigeria News (News Reader)"] Check |url= value (help). Nigeria News (News Reader). 2020-10-16. Retrieved 2020-10-16. 
  5. "JUST IN: Nigeria’s Coronavirus cases slump further; total figures surpass 60,000". P.M. News. 2020-10-10. Retrieved 2020-10-16. 
  6. Ojoye, Taiwo (2019-08-18). "Many misuse social media –Mary Lazarus". Punch Newspapers. Retrieved 2020-10-16. 
  7. punchng (2017-07-02). "Modelling prevented me from making a first-class degree - Mary Lazarus". Punch Newspapers. Retrieved 2020-10-16. 
  8. "Winners Emerge @ 2018 City People Movie Awards". City People Magazine. 2018-09-24. Retrieved 2020-10-16. 
  9. "AMVCA 2020". Africa Magic - AMVCA 2020. 2020-02-06. Retrieved 2020-10-16.