Mary Nnena Njoku (bí ní ọjọ́ ogún, oṣù kẹta ọdún 1985) jẹ́ òṣèré àti adarí fún ilé iṣẹ́ ROK Studios ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[1] Óun ni ó gbé eré Thy Will be Done àti Husband of Lagos jáde, ó sì ṣe adarí fún eré Single Ladies àti Festac Town.

Mary Njoku
Ọjọ́ìbí20 Oṣù Kẹta 1985 (1985-03-20) (ọmọ ọdún 39)
Lagos, Nigeria
Orílẹ̀-èdèNàìjíríà Nigerian
Iṣẹ́
Ìgbà iṣẹ́2003-present
Olólùfẹ́Jason Njoku (married 2012)
Àwọn ọmọ3

Ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ àtúnṣe

Mary Njoku jẹ́ ọmọ kẹfà nínú àwọn ọmọ mẹ́jo tí àwọn òbí rẹ bí. Wọ́n bí sí ìlú Amuwo Odofin ní Ìpínlẹ̀ Èkó. Ó jẹ́ ọmọ Nsukka ní Ìpínlẹ̀ Ẹnúgu.[2] Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Amuwo Odofin High School. Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga tí Lagos State University níbi tí ó tí gboyè nínú ìmò èdè gẹ̀ẹ́sì. Njoku darapọ̀ mọ́ Nollywood ní ọdún 2003, nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún mẹ́tadínlógún [3].

Iṣẹ́ àtúnṣe

Njoku kópa nínú eré Home Sickness ní ọdún 2004, èyí sì ni eré tí ó má kọ́kọ́ ṣe. Ó di gbajúmọ̀ lẹ́yìn tí ó kópa nínú eré Blackberry Babes ní ọdún 2011.[4] Láàrin ọdún 2011 àti 2013, ó dá iRoktv kalẹ̀. Ní ọdún 2018, ó gbé eré rẹ̀ kalẹ̀ tí ó pè ní Nwanyioma.[5]

Ìgbésí ayé rẹ̀ àtúnṣe

Mary Njoku ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú Jason Njoku ní ọjọ́ kẹjidínlógún oṣù kẹjọ ọdún 2012. Ó ti bí ọmọ mẹ́ta.[6]

Àwọn Ìtọ́kàsi àtúnṣe