Mary Slessor
Mary Mitchell Slessor (Ọjọ́ kejì oṣù kejìlá ọdún 1848 si ọjọ́ kẹtàlá oṣù kínní ọdún 1915) jẹ ajihinrere si orílẹ̀-èdè Naijiria lati ilu Scotland. Ní kété tí o dé orílẹ̀-èdè Naijiria, Slessor bẹ̀rẹ̀ si kọ èdè Efik, ti o jẹ́ èdè ìbílẹ̀ níbẹ̀. Nítorí ìmò ti o ni nipa èdè ìbílẹ̀ yi ati ìsẹ̀dá rẹ gẹ́gẹ́ bi ẹni ti o nígbo'yà, Slessor rí ojú rere àwon ará ìlú náà o si rọrùn fun un lati tan ẹsin ọmọ lẹyin Kristi ka ti o si tun ni anfani lati ṣe agbatẹru ẹtọ àwon obìnrin àti àmójútó àwon ọmọde ni ilẹ̀ náà. Ohun ti o sọ ọ di gbajúgbajà ni bi o ṣe da aṣa pípa àwon ọmọ-ọwọ ti o jẹ ìbejì duro laarin àwon ẹ̀yà Ibibio, ni apa gúsù-ìlà-oòrùn orílẹ̀-èdè Naijiria.
Mary Slessor | |
---|---|
Mary Slessor | |
Ọjọ́ìbí | 2 December 1848 Aberdeen, Scotland |
Aláìsí | 13 January 1915 Use Ikot Oku, Itu, Akwa Ibom State, Nigeria formally known as Calabar province. | (ọmọ ọdún 66)
Orílẹ̀-èdè | Scottish |
Gbajúmọ̀ fún | Christian missionary work in Africa; promoting women's rights and rescuing children from infanticide. |
References
àtúnṣe- ↑ White, Donna (29 August 2010). "Red-hot designers hail Scots missionary for inspiring African style". The Daily Record. Retrieved 2011-09-06.
- ↑ Proctor, JH. Serving God and the Empire: Mary Slessor in South-Eastern Nigeria, 1876–1915. Brill. pp. 45–61. JSTOR 1581622.