Mary Uranta
Mary Data Uranta jẹ́ òṣèré àti olórin ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Wọn bíi sí ìlú Portharcourt, ibè sì ni ó gbé dàgbà. Ó wá lára àwọn tó díje fún ipò obìnrin tí ó rẹwà jùlọ ni ilẹ̀ Niger Delta, ó sì gbé ipò kejì. Uranta bẹ̀rẹ̀ ère ṣíṣe ni ọdún 2000 pelu eré Girls Hostel. Ní ọdún 2006, ó di gbajúmọ̀ fún ipá tí ó kó nínú eré Secret Mission. Ó dà egbe Mary Uranta Foundation kalẹ láti pèsè iranlọwọ fún àwọn ọmọdé ni ìlú Opobo. Ó ti gba ebun lati ọdọ City People Awards àti African Youth Ambassador Award.
Mary Uranta | |
---|---|
Uranta in 2013 | |
Ọjọ́ìbí | Mary Data Uranta Port Harcourt |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Rivers State University of Science and Technology |
Iṣẹ́ | Actress, model, film producer, singer |
Ìgbà iṣẹ́ | 2006—present |
Ọmọ ìlú | Queenstown-Opobo, Rivers State |
Ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeUranta dàgbà ni ìlú Portharcourt ni ìpínlè Rivers.[1] Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ tí Holy Rosary Girls Secondary school kí ó tó tesiwaju sì ilẹ̀ ẹ̀kọ́ gíga tí Rivers State University of Science and Technology níbi tí ó tí gboyè nínú ìmò Secretarial Administration.[2]
Awọn Itọkasi
àtúnṣe- ↑ Erhariefe, Tony (28 April 2013). "Mary Uranta: Sexual harassment drove me out of Nollywood". Sunnewsonline.com (Daily Sun). Archived from the original on 19 April 2014. https://web.archive.org/web/20140419015616/http://sunnewsonline.com/new/?p=24700. Retrieved 18 April 2014.
- ↑ "Why I'm scandal free – Mary Uranta". Vanguardngr.com (Vanguard Media). 12 November 2011. http://www.vanguardngr.com/2011/11/why-i%E2%80%99m-scandal-free-mary-uranta/. Retrieved 18 April 2014.