Matilda Kerry jẹ́ onímọ̀ ìṣègùn òyìnbó[1] àti asọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ ìmóhùn máwòrán, ó wà lára àwọn tí ó ń ṣe ètò The Doctors. Ó gbajúmọ̀ nígbà tí ó gba àmì-ẹ̀yẹ obìnrin tó rẹwà jù ní Nàìjíríà ní ọdún 2000.[2]

Ẹ̀kọ́

àtúnṣe

Kerry lọ ilé ìwé Federal Girls College, ti Benin, ibẹ̀ ni ó ti gba ìwé ẹrí WAEC rẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà tí ó parí ẹ̀kọ́ Sẹ́kọ́ndìrì rẹ̀, ó tẹ ẹ̀kọ́ rẹ̀ síwájú ní Yunifásítì ìlú Èkó láti kọ́ nípa ìmọ̀ ìṣègùn òyìnbó.

Iṣẹ́ rẹ̀

àtúnṣe

Kerry kàwé gboyè ní Yunifásitì ìlú Èkó ní ọdún 2006 láti di Dókítà alábẹ́rẹ́. Òun ni Ààrẹ George Kerry Life foundation,[3] àjọ tí ó ń kọ́ àwọn ènìyàn nípa àwọn àìsàn tí kò sé kó ràn.[4][5]

Ó wà lára àwọn Young African Leaders Initiative, ètò tí ààrẹ Amerika tẹ́lẹ̀rí, Barack Obama dá kalẹ̀.

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Nigerian public health doctors - FamousFix.com list". FamousFix.com. Retrieved 2022-04-26. 
  2. "Search | Britannica". www.britannica.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-04-26. 
  3. "Dr. Matilda Kerry | Docsays". www.docsays.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2017-08-29. Retrieved 2017-08-29. 
  4. I am not conscious of fashion –Matilda Kerry Archived 2012-11-19 at the Wayback Machine.
  5. "GEORGE KERRY LIFE FOUNDATION". GEORGE KERRY LIFE FOUNDATION. Archived from the original on 2017-08-29. Retrieved 2017-08-29.