Mbege jẹ́ ohun mímu ti ọlọ́gẹ̀dẹ̀ tí ó jẹ́ ti ìbílẹ̀ Chagga ti ẹ̀yà Tanzania tí ó wà ní agbègbè Kilimanjaro. Ó jẹ́ ọtí tí a se láti ara ọ̀gẹ̀dẹ̀ tí ó ti toró bananas. Ìgbésẹ̀ ṣíṣe mbege le gidi gan-an ó sì máa ń gba ni ní àkókò bí ó ti jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbésẹ̀ náà ní ó ń di ṣíṣe pẹ̀lú ọwọ́ láìsí ìrànlọ́wọ́ ohun èlò ẹ̀rọ ìgbàlódé. Adùn ìpìlẹ̀ mbege ni wọ́n sọ pé ó jẹ́ dùn èyí tí ìkorò díẹ̀ sì máa ń tẹ̀lé e lẹ́yìn rẹ̀.

Ìgbésẹ̀

àtúnṣe

Ọ̀gẹ̀dẹ̀ náà máa ń di gígún lẹ́yìn náà yóò wá di ṣíṣè nínú ìkòkò ìdáná lórí iná fún ó lé ní wákàtí mẹ́fà. Ohun èlò náà yóò wá di bíbò yóò sì di fífi síta láti toró ferment fún bí ọjọ́ méje. Àpòpọ̀ tí ó ti toró yìí máa ń di dídì pọ̀ látara koríko àti ewé ọ̀gẹ̀dẹ̀ àti àsáró tí ó ki tí a se láti ara ìyẹ̀fun ọkà bàbà omi sì máa ń di fífi kún un. Ìyẹ̀fun quinine-bark díẹ̀ yóò wá di fífi kún àpòpọ̀ náà kí ó ba à lè dín adùn ọ̀gẹ̀dẹ̀ náà kù. Yóò wá di fífi sílẹ̀ láti wà ní ìta fún ọjọ́ mìíràn síwájú kí ó tó lè di jíjẹ.

Nínú àṣà tó gbajúgbajà

àtúnṣe
  • Ìgbésẹ̀ ṣíṣe mbege di ṣíṣe lórí ìfihàn Travel Channel Bizarre Foods with Andrew Zimmern.

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe