Memry Savanhu
Memry Savanhu (tí a tún le kọ bíi Memory Savanhu ) jẹ́ òṣèré Nollywood ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Sìmbábúè, olùgbéré-jáde, àti olùṣòwò tí ó n gbé ní ìlú Èkó, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, lẹ́hìn tí ó kó kúrò ní ìlú Lọ́ndọ̀nù. Ó ṣe àkọ́kọ́ ipa fíìmù rẹ̀ nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Distance Between ní ọdún 2008.[1] Ó ti wá ṣe bẹ́ẹ̀ kópa nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn fíìmù Nollywood láti ìgbà náà tó fi mọ́ One Fine Day[2], On Bended Knees[3] àti '76. Òun ni olùdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ agbéréjáde kan tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Memkay Productions.[4][5][6]
Memry Savanhu | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Memry Savanhu Zimbabwe |
Orílẹ̀-èdè | Zimbabwean |
Iṣẹ́ | |
Ìgbà iṣẹ́ | 2008 - present |
Gbajúmọ̀ fún |
|
Ètò ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeA gbọ́ wípé orílẹ̀-èdè Sìmbábúè ni wọ́n bí Savanhu sí, ó sì sọ di mímọ̀ pé ẹ̀yà Zezuru ni òún jẹ́. Ó kọ́ ẹ̀kọ́ ìmọ̀ eré ṣíṣe ní ìlú Lọ́ndọ̀nù àti ìmọ̀ fíìmù ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga New York Film Academy tí ó wà ní Abu Dhabi, UAE.[7]
Iṣẹ́ rẹ̀
àtúnṣeSavanhu ṣe àgbéjáde àkọ́kọ́ fíìmù rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ n ṣe Distance Between ní ọdún 2008. Olùdarí eré náà ni Izu Ojukwu tí àwọn olùkópa síì pẹ̀lú Rita Dominic, Mercy Johnson, Kalu Ikeagwu àti Yemi Blaq. Lára àwọn eré rẹ̀ míran tí ó gbé jáde ni One Fine Day, Cougars Reloaded, Catwalq àti On Bended Knees. Ní ọdún 2016, ó kópa gẹ́gẹ́ bi "Eunice" nínu eré Izu Ojukwu kan tító dá lóri ìtàn ogun tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ '76.[8] Àwọn olùjọkópa rẹ̀ tún pẹ̀lú Rita Dominic, Ramsey Nouah, Chidi Mokeme, Ibinabo Fiberesima àti Daniel K. Daniel. Fíìmù náà jáde ní 3 Oṣù Kọkànlá, Ọdún 2016.[9][10][11]
Ní ọdún 2014, wọ́n yàán fún àmì-ẹ̀yẹ "Best Actor UK Female" níbi ayẹyẹ Zulu African Academy Awards (ZAFAA), tí ó wáyé ní Ìlú Lọ́ndọ̀nù fún ipa rẹ̀ nínu fíìmù Maria's Vision. [12]
Ní ọdún 2015, wọ́n tún yàán fún àmì-ẹ̀yẹ Sìmbábúè International Women Awards (ZIWA) tí ó wáyé ní ìlúBirmingham tí ó wà ní UK ní Oṣù Kẹẹ̀wá ọdún náà, gẹ́gẹ́bí ìwé ìròyìn The Herald ti Sìmbábúè ti ṣe gbe síta.[13]
Àwọn eré rẹ̀
àtúnṣeÀwọn sinimá àgbéléwò rẹ̀
àtúnṣeỌdún | Fíìmù | Ipa | Akọ́sílẹ̀ | Ìtọ́kasí |
---|---|---|---|---|
2016 | '76 | Actress (Eunice) | Drama, Romance | [14][15] |
2015 | One Fine Day | Actress | Drama, Romance | [16] |
2014 | Maria's Vision | Actress (Maria) | Romance, Drama | [17] |
2013 | On Bended Knees | Actress | Drama | [18] |
2009 | Nnenda | Actress | Drama | [19][20] |
2008 | Distance Between | Producer | Romance, Drama | [21] |
Eré tẹlifíṣọ̀nù rẹ̀
àtúnṣeỌdún | Fíìmù | Ipa | Àkọsílẹ̀ | Ìtọ́kasí |
---|---|---|---|---|
2012 - | Catwalq (also Lagos Catwalk) | Actress | TV series, Soap opera, Drama | [22][23][24] |
Àwọn ìgbóríyìn rẹ̀
àtúnṣeỌdún | Ayẹyẹ | Àmì-ẹ̀yẹ | Èsì |
---|---|---|---|
2015 | ZIWA | Nollywood contribution | Yàán |
2014 | ZAFAA | Best Actor UK Female | Yàán |
Ọ̀rọ̀ ayé rẹ̀
àtúnṣeÌwé ìròyìn Pulse Nigeria jẹ́ kó di mímọ̀ wípé Savanhu ti kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ti ní àwọn ọmọ méjì.[25]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Distance Between". Nollywood REinvented. Retrieved November 18, 2020.
- ↑ "One Fine Day". Nollywood REinvented. Retrieved November 18, 2020.
- ↑ "On Bended Knees". Nollywood REinvented. Retrieved November 18, 2020.
- ↑ Kachingwe, Kelvin (August 17, 2014). "Zambian author writes Zim movie". Zambia Daily Mail. Retrieved November 19, 2020.
- ↑ "Local Film Premieres in UK". Zimbabwe Online News. August 22, 2014. Archived from the original on October 8, 2021. Retrieved November 19, 2020.
- ↑ Mamazita! (January 20, 2011). "Five upcoming actresses to look out for in 2011!". Naija Rules!. Archived from the original on October 8, 2021. Retrieved November 19, 2020.
- ↑ "Memry Savanhu: From Zimbabwe with love". Guardian. November 19, 2016. Retrieved November 18, 2020.
- ↑ Okoroafor, Cynthia (November 12, 2016). ""IT'S A VERY EXCITING TIME FOR NOLLYWOOD", SAYS CHIOMA UDE, AFRIFF FOUNDER, AS THE FILM FESTIVAL "EMBRACES THE WORLD" THIS YEAR". Ventures Africa. Retrieved November 18, 2020.
- ↑ Augoye, Jayne (October 24, 2016). "Nollywood flick, 76, gets more laurel". Premium Times. Retrieved November 18, 2020.
- ↑ Izuzu, Chibumga (September 11, 2016). "War drama "76" reveals an adept actress you should know". Pulse Nigeria. Retrieved November 18, 2020.
- ↑ Mamazita! (January 20, 2011). "Five upcoming actresses to look out for in 2011!". Naija Rules!. Archived from the original on October 8, 2021. Retrieved November 19, 2020.
- ↑ "ZAFAA Global Awards 2014 Nominees announced". Zafaa.org. Archived from the original on October 8, 2021. Retrieved November 19, 2020.
- ↑ Tanyanyiwa, Peter (September 23, 2015). "Zimbabwe: Zim Actress Shines in Nigeria". All Africa. Harare: The Herald. Retrieved November 18, 2018.
- ↑ "ANOTHER GREAT "NOLLYWOOD" FILM FOR THIS YEAR'S TIFF-GOERS TO SEE". Fordham PR. Retrieved November 18, 2020.
- ↑ "'76 (2016)". IMDb. Retrieved November 18, 2020.
- ↑ "One Fine Day". Nollywood REinvented. Retrieved November 18, 2020.
- ↑ "Local Film Premieres in UK". Zimbabwe Online News. August 22, 2014. Archived from the original on October 8, 2021. Retrieved November 19, 2020.
- ↑ "On Bended Knees". Nollywood REinvented. Retrieved November 18, 2020.
- ↑ "NNENDA (2009) - Film en Streaming |The best full movies playing, online and free.". French TV Movies. Retrieved November 19, 2020.
- ↑ "Nnenda (2009)". IMDb. Retrieved November 18, 2020.
- ↑ "Distance Between". Nollywood REinvented. Retrieved November 18, 2020.
- ↑ "Lagos Catwalk". TVDb. Retrieved November 18, 2020.
- ↑ "Lagos Catwalk". TV Time. Archived from the original on October 8, 2021. Retrieved November 18, 2020.
- ↑ "PHOTOS: MEDIA LAUNCH OF CATWALQ TV SERIES". Loladeville. February 6, 2012. Archived from the original on October 8, 2021. Retrieved November 19, 2020.
- ↑ Izuzu, Chibumga (September 11, 2016). "War drama "76" reveals an adept actress you should know". Pulse Nigeria. Retrieved November 18, 2020.
Àwọn ìtakùn Ìjásóde
àtúnṣe- Memry Savanhu on IMDb
- Memry Savanhu Archived 2021-10-08 at the Wayback Machine. on Flixanda
- Memry Savanhu on Nollywood Reinvented.
- Zimbabwean-born Actress ‘Memry Savanhu’, based in London Relocated Fully to Lagos, Nigeria to act in Nollywood Films – Check Out Her Photos! on Golden Icon
- Memry Savanhu on Search.co.zw
- Jara: Memry Savanhu on Africa Magic