Modupe Omo-Eboh
Modupe Omo-Eboh (ọdun 1922 – ọjọ́ karúndínlọ́gbọ̀n oṣù kejì ọdun 2002) jẹ́ agbẹjọ́rò ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Ọ̀jọ̀gbọ́n amòfin tí ó jẹ́ adájọ́bìnrin àkọ́kọ́ ní orílẹ̀ èdè náà.
Ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́
àtúnṣeWọ́n bí Modupe Akingbehin sí ìpínlẹ̀ Èkó ní ọdún 1922. Ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ-ọmọbìnrin Oshodi Tapa gbajúgbajà l'Èkó àti ọmọọmọ-ọmọbìnrin ti Bishop Samuel Ajayi Crowther, tí òun fúnra rẹ̀ jẹ́ àwọn ọmọ Ọba Abiodun ti Ọ̀yọ́. Herbert Macaulay ni arákùnrin ìyá rẹ̀.[1] Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Queen's College, ti Èkó kí ó tó lọ kọ́ ẹ̀kọ́ ìmọ̀-òfin ní ìlú-Ọba.[2]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Significant milestone - The Nigerian Observer, 15th November 1969, pg2.". 18 October 2017.
- ↑ Ajibla-Ogundip, Phebean (2012). Up-Country Girl: A Personal Journey and Truthful Portrayal of African Culture. AuthorHouse. p. 135. ISBN 9781468584738. https://books.google.com/books?id=WSAd1s8VH34C.