Mọfọ́lọ́jì èdè Yorùbá

(Àtúnjúwe láti Mofoloji ede Yoruba)

Mọfọ́lọ́jì: Harrison Adéníyì Ọjú-Ìwé 71-100.

Ìfáárà

Ìpele tàbí ìsọ̀rí márùn-ún ni a lè pín gírámà èdè sí.[1] Àwọn ìpèle yìí náà ni fònẹ́tíìkì tàbí ètò ṣíṣàpèjúwe ìró, fonọ́lọ́jì tàbí ìbáṣepọ̀ ìró; sẹ̀méńtíìkì tabí èt`o ìtumọ̀; síntáàsì tàbí ètò tí ó dale gbólóhùn, àti mọfọ́lọ́jì tabí ètò nípa ṣíṣẹ̀dá ọ̀rọ̀. Gbogbo àwọn ìpele wọ̀nyí ni ó ní ìbáṣepọ̀ tí ó ṣòro láti yà sọ́tọ̀.[2]

Ifunniloruko

àtúnṣe

Ìfúnnilórúkọ ní Èdè Yorùbá: Olú Àlàbá Ọjú-Ìwé 101-116.

Ìfáárà

Ní àwùjọ adúláwọ̀ káàkiri ayé, orúkọ ṣe pàtàkì púpọ̀. Ojú ayé nìkan kọ́ ni a fi í wò ó; a máa fi ojú-inú àti ojú ẹ̀mí pàápàá wò ó. Nítorí náà orúkọ jẹ mọ́ ìhun ọ̀rọ̀-orúkọ nínú èdè adúláwọ̀ kọ̀ọ̀kan; ó jẹ mọ́ ìmọ̀lára ènìyàn, ó jẹ mọ́ ìgbàgbọ́, ìfẹ́, àníyan àti ìrètí ènìyàn pẹ̀lú....

Amulo ede Yoruba

àtúnṣe

Àmúlò (Èdè Yorùbá) Dèjì Médùbi Ojú-Ìwé 117-129.

Ìfáárà

Èdè, èdè, èdè láìsí èdè, èèyàn kò sunwòn láwùjo. Eròngbà wa nínú aròko yìí ni láti tanná sí àmúlò èdè Yorùbá ní orísirísi ònà. A kò gbìdánwò láti parí isé síbí, nítorí náà, ìpàjùbà lásán ni eyí jé fún isé ribiribi tó wa níwájú....

Aayan ogbufo

àtúnṣe

Aáyan Ògbufọ̀: Ayọ̀ Yusuff Ọjú-Ìwé 130-144.

Ìfáárà

Tí ènìyàn bá ṣe alábàápàdé àkọsílẹ̀ kan tí wọ́n ṣe ní èdè tó ṣe àjòjì sí i, ọ̀nà àbáyọ tí yóò kọ́kọ́ wá sọ́kan rẹ̀ ni ìranwọ́ ẹni tí yóò ṣe aáyan ògbufọ̀ irú àkọsílẹ̀ bẹ́ẹ̀. A le sọ pé iṣẹ́ ògbufọ̀ ni ó fẹ́rẹ̀ nira jùlọ nínú gbogbo iṣẹ́. ...

Apola oruko

àtúnṣe

Àpólà Orúkọ (ní Èdè Yorùbá): títí Sàlámì Ọjú-Ìwé 145-

Ìfáárà

Àpólà-orúkọ ni ẹyọ ọ̀rọ̀ tàbí àsopọ̀ ọ̀rọ̀ tí a le lò gẹ́gẹ́ bí olùwà, àbọ̀ tàbí àbọ̀-atọ́kùn nínú gbólóhùn aṣeégbà. A lè fi ipò mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí hàn nínú àwọn àpẹẹrẹ ìsàlẹ̀ yìí.


Iwe ti a yewo

àtúnṣe

Harrison Adéníyì (2000) Ìlò Èdè àti Ẹ̀dá-Èdè Yorùbá Olu Akin Printing Press. ISBN 978-047-386-6. Ìmọ̀ Ẹ̀dá-Èdè àti Èdè Yorùbá: Harrison Adéníyì & títí Ọnàdípẹ̀ Ọjú-Ìwé 1-23.[3]

Àwọn Ìtọ́ka sí

àtúnṣe
  1. "Morphology - an overview". ScienceDirect Topics. 2016-01-01. Retrieved 2020-03-27. 
  2. Wagner, Dr. Jennifer. "What is Morphology? - Introduction to Linguistics". ielanguages.com. Retrieved 2020-03-27. 
  3. "What is Morphology? – All About Linguistics". All About Linguistics. Archived from the original on 2020-03-04. Retrieved 2020-03-27.