Moody Arthur Awori (tí a bí ní oṣù Kejìlá ọdún 1928) tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ gẹ́gẹ́ "Uncle Moody", jẹ́ olóṣèlú ọmọ orílẹ̀ ède Kenya tí ó jẹ́ igbá kejì ààrẹ orílẹ̀ ède Kenya láti ọjọ́ Kàrúndínlógbọ̀n oṣù kẹsàn-án ọdún 2003[1] di ọjọ́ kẹsàn-án oṣù Kínní ọdún 2008.[2] Òun ni ó kọ ìwé Riding on a Tiger,.

Moody Awori
Fáìlì:Moody Awori.jpg
9th Vice President of Kenya
In office
25 September 2003 – 9 January 2008
ÀàrẹMwai Kibaki
AsíwájúMichael Kijana Wamalwa
Arọ́pòKalonzo Musyoka
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí5 Oṣù Kejìlá 1928 (1928-12-05) (ọmọ ọdún 96)
Busia, Kenya
(Àwọn) olólùfẹ́Rose Awori
ẸbíAggrey Awori (brother)
Susan Wakhungu-Githuku (niece)
Judi Wakhungu (niece)
Àwọn ọmọ5
Alma materMakerere University

Òṣèlú

àtúnṣe

Ipò ijoba àkọ́kọ́ tí a yan Moody Awori sí ni lati ṣe aṣojú Ọkọ̀ FunyulaBusia District ní ọdún 1984.[1][3] Lábé ààrẹ Daniel arap Moi, o di ọ̀pọ̀lọpọ̀ ipò mú gẹ́gẹ́ bi ìgbá-kejì mínísítà.[1][3]

Awori fi ẹgbẹ́ òṣèlú Kenya African National Union kalẹ̀ láti dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú National Rainbow Coalition ní ọdún 2002, ó sì di ipò alága ọkàn lára àwọn ìgbìmọ̀ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú náà.[1] Nígbà tí Moi rọ́pò Mwai Kibaki, Awori di Mínísítà abẹlé ní oṣù Kínní ọdún 2003[3] kí ó tó di ìgbà kejì ààrẹ ní kẹsàn-án 2003, lẹ́yìn ìgbà tí ìgbà kejì ààrẹ tẹ́lẹ̀, Michael Kijana Wamalwa, fi ayé sílẹ̀ ní London.[1]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 Page on Awori at Vice-President web site Archived 2007-09-27 at the Wayback Machine..
  2. "Awori Hands Over to Kalonzo", The East African Standard, 10 January 1998.
  3. 3.0 3.1 3.2 Kenya Parliament profile Archived 2006-04-14 at the Wayback Machine..