Morayo Afolabi Brown
Morayo Afolabi-Brown jẹ́ olóòtú ètò orí tẹlifíṣọ́ọ̀nù. Ó ti fìgbà kan jẹ́ olùdarí kejì fún ètò iṣẹ́ ní TVC kí ó tó fiṣẹ́ náà sílẹ̀ ní ọdún 2019, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olóòtú ètò "Your View". [1] [2]
Morayo Afolabi-Brown | |
---|---|
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Rutgers University |
Iṣẹ́ | Producer |
Olólùfẹ́ | Brown Kabiti ( m.present) |
Parent(s) |
|
Ìgbésí ayé àti ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeMorayo Afolabi-Brown tí ó jẹ́ gbajúgbajà olóòtú ètò àràárọ̀ "Your View" lórí tẹlifíṣọ́ọ̀nù lọ sí Rutgers University, the State University of New Jersey láti kẹ́kọ̀ọ́ lórí Political Science.[3] Àwòkọ́ṣe ìyá rẹ̀ ni ó tẹ̀lé kí ó tó wà ka ìwé nípa Abike Dabiri, Ngozi Okonjo-Iweala, Ibukun Awosika, Oprah Winfrey àti Chimamanda Ngozi Adichie tí ìgbésí ayé wọn wú u lórí.[4]
Iṣẹ́ rẹ̀
àtúnṣeMorayo Afolabi-Brown bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tó yàn láàyò ní ọdún 2005 gẹ́gẹ́ bíi Client Service Manager ní CMC Connect kí ó tó tẹ̀ síwájú lọ sí CUE Media níbi tí ó ti jẹ́ Head of Content and Development kí ó tó ṣẹ̀ wá di Senior Executive, Marketing and Research. Ó ti kópa nínú fíìmù àgbéléwò àti ètò orí afẹ́fẹ́ lóríṣiríṣi. Ó ti fìgbà kan jẹ́ Business Development Manager kí ó tó wá di Head of Content and Channels Acquisition ní HiTV kí wọ́n tó wá gbà á síṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi Deputy Director of Programmes ní TVC.[5] [6]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Ojo, Hannah. "My mission is to reorientate women and young people". The Nation Newspaper. https://thenationonlineng.net/my-mission-is-to-reorientate-women-and-young-people/. Retrieved 9 May 2020.
- ↑ Alure. "TV HOST, MORAYO BROWN CLARIFIES WHEN SHE RESIGNED APPOINTMENT WITH TVC". Allure By Vanguard Newspaper. https://allure.vanguardngr.com/2019/05/clarify/. Retrieved 9 May 2020.
- ↑ The Nation Newspaper (September 8, 2013). "My mission is to reorientate women and young people". The Nation Newspaper. https://thenationonlineng.net/my-mission-is-to-reorientate-women-and-young-people/. Retrieved 9 May 2020.
- ↑ The Nation Newspaper (September 2, 2018). "Morayo Afolabi Brown". The Nation Newspaper. https://thenationonlineng.net/morayo-afolabi-brown/. Retrieved 9 May 2020.
- ↑ Diamond, Maria (18 January 2020). "‘I’ve been bruised, dissed, bashed and even fired. Looking back, it was all worth it’". Guardian Newspaper. Archived from the original on 8 December 2023. https://web.archive.org/web/20231208200410/https://guardian.ng/guardian-woman/ive-been-bruised-dissed-bashed-and-even-fired-looking-back-it-was-all-worth-it/. Retrieved 9 May 2020.
- ↑ The Nation Newspaper (September 8, 2013). "My mission is to reorientate women and young people". The Nation Newspaper. https://thenationonlineng.net/my-mission-is-to-reorientate-women-and-young-people/. Retrieved 9 May 2020.