Moyegeso jẹ́ Ọba ìlú Itele ní Ijebu, ní Ìpínlẹ̀ Ògùn, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Moyegeso tó wà lórí oyè lásìkò tí a ń kọ àyọkà yí ni Ọba Mufutau Adesanya Kasali Iboriaran Kinni, láti ìdílé Ishagbola. Ó gun orí oyè ní ọjọ́ kẹta oṣụ̀ kẹta ọdún 2003. Ọba Jones Adenola Ogunde Adeyoruwa II láti ìdílé Adeyoruwa ló sì wa lórí oyè tẹ́lẹ̀. Ọba yìí jọba láti ọdún 1981 wọ ọdún 1996. Ìran Awujale Oba Moyegeso ni gbogbo àwọn Moyegeso ti Itele tó ti fìgbà kan jẹ, tó jẹ ọba láti ọdún 1710 wọ 1725), tí àwọn ènìyan sì mọ̀ sí Ojigi Amoyegeso, [1] èyí tó jẹ́ Awujale ti ìlú Ìjẹ̀bú ẹlẹ́ẹ̀kọkànlélógójì. Ọmọ-ọba tó sì máa jẹ oyè yìí gbọ́dọ̀ jẹ ọmọ Idewon, níbi tí Awujale Oba Ojigi Amoyegeso ti wá. Ìdílé ọlọ́ba méjì ni ó wà, tí wọ́n ti máa ń yan Ọba ìlú yìí. Àwọn náà ni:

  • Ìdílé Adeyoruwa.
  • Ìdílé Ishagbola.
Moyegeso Installing Otunbas in 2011

Àwọn ìran Moyegeso wà lára Ìdílé Moyegeso ní Idewon, èyí tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìdílé mẹ́rin tí wọ́n ti lè yan Awujale ti Ìjẹ̀bú.[2]

Ààfin Ọba

àtúnṣe

Oba Moyegeso ti Itele ní àwọn ìjọye, lára wọn sì ni àwọn Ọ̀túnba. Káàkiri ilẹ̀ Itele ni wọ́n sì ti wá. Tí a bá ni ka to àwọn ìjòyè yìí nípele-nípele, Otunba Wayoruwa láti Agbodu ni igbá kejì lẹ́yìn Moyegeso. Àmọ́ ṣá, kol lè delé nípò Ọba tàbí tí Ọba bá wàjà. Bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n ní Olootu ti Itele, tí ó fìgbà kan jẹ́ Odele ti Odole, tó jẹ́ olórí àwọn afọbajẹ.

Ìtẹ́ Ọba

àtúnṣe

Odole ni ìtẹ Ọba àti ààfin rẹ̀ wà.[3] Ìwádìí fi lélẹ̀ pé Ààfin Moyegeso ni ó tóbi jù lọ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà,[4] èyí tí wọ́n fi ilẹ̀ méjìlélógún kọ́ ní Ijebu-Itele.

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe