Mufutau Gbadamosi Esuwoye II
Mufutau Gbàdàmọ́sí Èsúwọyè II tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹjọ, ọdún 1963 jẹ́ Ọba Ọlọ́fà ti ìlú Ọ̀fà ẹlẹ́kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ní Ìpínlẹ̀ Kwara ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà .[1]
Ibibi
àtúnṣeWọ́n bí Mufutau Gbadamosi Esuwoye kejì ní ọjọ́ Kẹwàá oṣù keje ọdún 1963 sí ẹbí Alhaji Muhammed Gbadamosi Esuwoye àti Alhaja Awawu Gbadamosi Esuwoye, ti ìdílé Obatiwajoye àti Asalofa ní ìjọba ìbílẹ̀ Ọ̀fà ní Ìpínlẹ̀ Kwara ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeỌba Mufutau, lọ sílé ẹ̀kó Maru Teachers College, tí ó wà ní ìlú Gusau, láàrín ọdún 1976 sí 1981, níbi tí ó ti gba ìwé-ẹ̀rí Olukoni grade II. Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti Birni-Kebbi láàrín ọdún 1982 àti 1985 fún ìwé-ẹ̀kọ́ gíga ti orílẹ̀-èdè (ND) nínú ìmọ̀-ilé. Ní ọdún 1989 ó gba oyè nínú ìmọ̀-ẹ̀rọ Ilé láti Ile-ẹkọ giga Ahmadu Bello, ní ìlú Zaria.
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2023-12-24. Retrieved 2023-12-24.