Muhammad Auwal Albani Zaria

Muhammad Auwal Adam tí àwọn ènìyàn tún mọ̀ sí Albani Zaria. Wọ́n bí i ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹsàn an ọdún 1960, ó sì kú ní ọjọ́ kínní osù kejì ọdún 2014 jẹ́ onímọ̀ nínú ẹ̀sìn Islam ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó kúndùn ìmọ̀ Hadith àti Fiqh.[1] Ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ òfin ẹ̀sìn, ìmọ̀ ìbá-ọ̀pọ̀ ènìyàb sọ̀rọ̀ telecommunications, engineering àti ICT. Ó fìgbà kan jé gbajúmọ̀ onímọ̀ Islamàti adarí ẹgbẹ́ Salafi ní Nàìjíríà. Ó fìgbà kan ṣiṣẹ́ aranṣọ nígbà tí ó sì kéré. Òun ni onímọ̀ àkọ́kọ́ tó máa fi "Salafiyah" pe àwọn onímọ̀ àti akẹ́kọ̀ọ́ Islam ní Nàìjíríà.[2] Ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ Islam mìíràn máa ń ṣe àpejúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i onímọ̀ Salafi tó ga jù lọ ní Nàìjíríà.[3]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. The man sheikh AlbaniDaily Trust Archived 2019-05-17 at the Wayback Machine.
  2. "Sheikh Albaniy Zaria – DHSN – Daarul Hadeethis Salafiyyah Nigeria" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-05-26. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  3. "DARUL QURAN LITAHFIZIL QURAN 44 ZARIA NIGERIA: HISTORY OF ALBAN". Darul Qur'an lil Tahfiz. 2014-08-22. Retrieved 2023-02-08.