Àdàkọ:Infobox religious biography Muhammadi Begum (tí a tún mò sí Sayyidah Muhammadi Begum; 22 May 1878 – 2 November 1908) ó jé onímò ìjìnlè mùsùlùmí Sunni Sunni Muslim, ònkòwé Urdu àti alágbàso fún èkó obìnrin. Ó se àjodásílè ìwé ìròhìn òsè ti mùsùlùmí tí a mò sí Tehzeeb-e-Niswan, tí ó sì jé olóòtú olùdásílè ìwé ìròhìn náà. Ó jé mímò gégé bíi obìnrin àkókó tí ó se olóòtú ìwé ìròhìn Urdu. Ó jé ìyàwó Sayyid Mumtaz Ali Deobandi.

Ìtàn ìdílé

àtúnṣe

Muhammadi Begum ni a bí ní ojó kejìlélógún, osù karùn odún 1878 ní Shahpur, Punjab.[1] Ó kó èdè Urdu tí ó sì di Hafiz bí ó se kó àkósórí Quran. Ó kó láti ko létà láti máa bá ègbón rè obìnrin s'òrò nígbà tí ó se ìgbéyàwó ní odún 1886.[2]

Ní odún 1897, ó di ìyàwó kejì fún Sayyid Mumtaz Ali Deobandi, onímò Islam àti akékò jáde ní ilé-èkó Darul Uloom Deoband.[3][4] Ó kó èdè Lárúbáwá àti èdè pásíà nípasè oko rè titun tí ó sì kó èkó gèésì, Hindi àti ìsirò[5] ní ìkòkò.

Ní ojó kíní, osù keje odún 1898, oko àti ìyàwó yíí bèèrè ìwé ìròhìn òsè fún àwon obìnrin tí wón n pè ní Tehzeeb-e-Niswan, tí wón mò sí òkan nínú àwon isé àkókó l'óri àwon ètó àwon obìnrin nínú èsìn Islam.[6] Ìwé ìròhìn yí se àtèjáde àwon èrò tí ó fa àríyànjiyàn nípa ìkòsílè oko àti aya divorce pèlú owó ìtójú obìnrin tí a kò alimony láti d'èkun ìda aso bo obìnrin purdah àti fífé ìyàwó púpò polygamy. Àwon ènìyàn yìn-ín gégé bíi omo orílè-èdè India obìnrin àkókó tí ó se àtìlehìn fún àwon òfin tí ó fún obìnrin[7] ní àyè kàn náà bíi okùnrin l'àwùjo àti obìnrin àkókó tí ó se olóòtú ìwé ìròhìn Urdu.[4] Ó se olóòtúTehzeeb-e-Niswan títí di ojó ikú rè ní odún 1908.[8]

Isé ìwé

àtúnṣe

Muhammadi Begum Begum se ònkòwé ogbòn ìwé bíi Shareef Beti tí ó s'isé l'óri ewu títo oko fún àwon omo obìnrin kékéèké tí ó máa n mú ìgbéyàwó[5][1] tipátipá wá. Àwon isé rè míràn ni:[5]

  • Aaj Kal
  • Safia Begum
  • Chandan Haar
  • Aadab e Mulaqaat
  • Rafeeqe Aroos
  • Khaanadari
  • Sughar Beti

Ikú àti Àsesílè

àtúnṣe

Ní omo ogbòn odún, Muhammadi Begum kú ní Shimla ní ojó kejì, osù kokànlá odún 1908.[4] Omo omo rè Naeem Tahir se àkójopò ìtàn ayé rè Sayyidah Muhammadi Begum awr Unka Khandan (Àdàkọ:Translation).[9] Omo rè okùnrin Imtiaz Ali Taj tí ó bí ní odún 1900. Ó fún ní ìnagije "Mera Taj" (Adé mi) nígbà tí àkókò tó, yóò olùko eré orí ìtàgé asáájú tí ó sì yan orúko ìnagije "Taj" náà l'áàyò gégé bíi ara orúko rè.[10] Omo rè obìnrin, Waheeda Begum, di olóòtú ìwé ìròhìn rè l'eyìn tí ó ti kojá lo. L'éyìn odún péréte ni Imtiaz Ali Taj gba ìsàkóso.[11]

Àtókasí

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 Sarwat Ali (10 May 2020). "Stuff legends are made of". The News International. https://www.thenews.com.pk/tns/detail/655864-stuff-legends-are-made-of. 
  2. Sarkar, Sumit; Sarkar, Tanika (2008). Women and Social Reform in Modern India: A Reader. p. 363. ISBN 9780253352699. https://books.google.com/books?id=GEPYbuzOwcQC&q=mumtaz+ali+deobandi&pg=PA360. Retrieved 20 August 2020. 
  3. Nayab Hasan Qasmi. "Mawlana Sayyid Mumtaz Ali Deobandi". Darul Uloom Deoband Ka Sahafati ManzarNama. Idara Tehqeeq-e-Islami, Deoband. pp. 147–151. 
  4. 4.0 4.1 4.2 Rauf Parekh (2 November 2015). "Muhammadi Begum and Tehzeeb-e-Niswan". Dawn. https://www.dawn.com/news/1216870. 
  5. 5.0 5.1 5.2 Farrukhi, Asif (2018-09-16). "NON-FICTION: A PIONEERING WOMAN OF LETTERS". DAWN.COM (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-05-04. 
  6. Moaddel, Mansoor (1998). "Religion and Women: Islamic Modernism versus Fundamentalism". Journal for the Scientific Study of Religion 37 (1): 116. doi:10.2307/1388032. JSTOR 1388032. 
  7. Prasad, Amar Nath; Joseph, S. John Peter (2006) (in en). Indian Writing In English:Critical Rum.(part-2). Sarup & Sons. p. 255. ISBN 978-81-7625-725-1. https://books.google.com/books?id=HuXl77rkasoC&dq=muhammadi+begum&pg=PA255. 
  8. Tahir Kamran (8 July 2018). "Re-imagining of Muslim Women - II". thenews.com.pk. The News International. Retrieved 22 August 2020. 
  9. Asif Farrukhi (16 September 2018). "A PIONEERING WOMAN OF LETTERS". Dawn. https://www.dawn.com/news/1433254. 
  10. "Imtiaz Ali, the Taj of Urdu drama". DAWN.COM (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2009-04-14. Retrieved 2022-05-04. 
  11. "Re-imagining of Muslim Women - II | Political Economy | thenews.com.pk". www.thenews.com.pk (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-05-04. 

Àdàkọ:Authority control