Benito Mussolini

(Àtúnjúwe láti Mussolini Benito)

Benito Mussolini jẹ́ olóṣèlú ọmọ orílẹ̀ èdè Italia. Wọ́n bí Benito ní 1883. Ó kú ní ọdún 1945. Òun ni ó dá Fasisti sílẹ̀ ní Italy. Òun ni ó darí Italy ní 1922 sí 1943. Agbára ni ó fi ń darí ilẹ̀ náà (a dictator). It Duce tí ó dúró fún olórí (the leader) ni àwọn èyìn rẹ̀ máa ń pè é. Mussolini àti ìgbìmọ̀ Fascist Party ni wọn jọ ń darí Italy. Wọn kò gba alátakò kankan láyè.

Benito Mussolini
40th Prime Minister of Italy
In office
31 October 1922 – 25 July 1943
MonarchVictor Emmanuel III
AsíwájúLuigi Facta
Arọ́pòPietro Badoglio (Provisional Military Government)
First Marshal of the Empire
In office
30 March 1938 – 25 July 1943
Arọ́pòPietro Badoglio
Duce of the Italian Social Republic
In office
23 September 1943 – 26 April 1945
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí(1883-07-29)29 Oṣù Keje 1883
Predappio, Forlì, Italy
Aláìsí28 April 1945(1945-04-28) (ọmọ ọdún 61)
Giulino di Mezzegra, Italy
Ọmọorílẹ̀-èdèItalian
Ẹgbẹ́ olóṣèlúRepublican Fascist Party
(1943-1945)
National Fascist Party
(1921-1943)
Italian Socialist Party
(1901-1914)
(Àwọn) olólùfẹ́Rachele Mussolini
ProfessionPolitician, Journalist
Lati osi si otun, o le rii awọn ara ti ko ni igbesi aye ti oloselu Komunisiti tẹlẹ Nicola Bombacci, Duce Benito Mussolini, olufẹ oloootitọ rẹ Clara Petacci, minisita Alessandro Pavolini ati olokiki oloselu fascist Achille Starace, ni ifihan ni Plaza Loreto ni Ilu Milan ni ọdun 1945.

Gẹ́gẹ́ bí ajàfún-mèkúnnù (socialist) ni Mussohni ṣe wọ òṣèlú. Ó jẹ́ olóòtu ìwé-ìróyìn kan tí ó ń jẹ́ ní Avanti ṣùgbọ́n ní 1914, ó dá ìwé-ìroyìn tirẹ̀ sílẹ̀. Ó pè é ní IL Popolo d’Italia. Ní ọdún 1921 ni ó dá ẹgbẹ́ òṣèlú Fascist sile. Èrò tí ó ní nípa dídá ẹgbẹ́ òsẹ̀lú yìí sílẹ̀ ni láti lè tún Italy kọ́ kí ó sì sọ ọ́ di ìlú tí ó lágbára. Lẹ́yìn ìgbà tí àwọn Fascist rìn lọ sí Róòmù ní 1922 (‘Fascist March on Rome’), Ọba Victor Emmanuel III pe Mussoline láti wá gbé ìjọba tirẹ̀ kalẹ̀. Kò pẹ́ tí àwọn Fascist bẹ̀rẹ̀ síí darí ilẹ̀ Italy.

Àwọn ọmọ ogun Mussoline kọlu Ethopia ní 1905 wọ́n sì ṣẹ́gun ibẹ̀ lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjà tí ó gbóná. Kò pé tí Mussolini ní kí àwọn ọmọ ogun òun lọ ran General Franco lọ́wọ́ nínú ogun abẹ́lé ilẹ̀ Spain. Ní ọdún 1940, Italy bẹ̀rẹ̀ síí kópa nínú ogun àgbáyé kejì. Italy dúró gbá gbá gba ti Germany ṣùgbọ́n wọ́n ṣẹ́gun Italy. Won di ebi ifidírẹmi Italy yìí ru Mussolini. Wọ́n gba ìjọba lọ́wọ́ rẹ̀ wọ́n sì sọ ọ́ sí ẹ̀wọ̀n. Àwọn German gba á sílẹ̀ ó wa di olórí ìjọbá tí kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ kan. Ní ọdún 1945, àwọn tí ó ń jà rí i mú, wọ́n sì pa á.