Muyiwa Ademola (a bi ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ́n, Oṣù Ṣéẹ́rẹ́ ọdún 1971) jẹ́ ògbóǹtarìgì òṣèré àti olùdarí sinimá àgbéléwò ọmọ Yorùbá lorílẹ̀èdè Nàìjíríà. Ní ọdún 2005, fíìmù rẹ̀ ORÍ gbá àmì-ẹ̀yẹ eré abínibí tó dára jù lọ ní 1st Africa Movie Academy Awards. Ní ọdún 2008, wọ́n yàn án fún àmì-ẹ̀yẹ òṣèrékùnrin abínibí tó peregedé julọ̀.

Muyiwa Ademola
Ọjọ́ìbíọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ́n, Oṣù Ṣéẹ́rẹ́ ọdún 1971
Ọmọ orílẹ̀-èdèNaijiria
Iléẹ̀kọ́ gígaYunifásítì Ìjọba Àpapọ̀ tí Ìlú Ibadan
Notable workAlápadúpẹ́


.[1][1]

Ibẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìgbé-ayé

àtúnṣe

A bí Muyiwa Ademola ni ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ́n oṣù Ṣẹ́ẹ́rẹ́, 1971 ní ìlú Abẹ́òkúta , tíì ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ògùn Ogun ní Nàìjíríà.[1]. O si lọ si St. David's High School ni Mọ̀lété ní Ìbàdàn ibi tí ó ti gba West Africa Secondary School Certificate.[2]. Ó tẹ̀síwájú sí Yunifásítì Ìjọba Àpapọ̀ tí Ìlú Ibadan ibi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ìmọ̀ Ẹ̀kọ́ Àgbà (B.ED) in Adult Education.

àtúnṣe

.[2]e.[3][4]

Iṣẹ́

àtúnṣe

Muyiwa Adémọ́lá ti ipasẹ̀ Charles Olúmọ tí a mọ̀ sí Àgbákò tí ó fi ìlú rẹ̀ Abẹ́òkúta .[5]. ṣe ibùgbé darapọ̀ mọ́ agbo àwọn òṣèré. Ó ṣe alábàápàdé olùdarí eré kan tí ó ń jẹ́ S. I Ọlá tí ó kọ ní eré ṣíṣe àti fíìmù gbígbé jáde. Ó bẹ̀rẹ̀ eré ṣíṣe rẹ̀ ní ọdún 1991.[6] Ní ọdún 1995, ó gbé eré rẹ̀ àkọ́kọ́ jáde ti ó pè ní Àṣìṣe. Iléeṣẹ́ Dibel ló ṣe àgbátẹrù eré náà. Láti ọdún 1995, ó ti gbé, darí àti hàn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré Yorùbá. Ní Ṣéẹ́rẹ́ ọdún 2013, ìròyìn sọ pé ó ní ìjàmbá ọkọ èyí tí ó kú díẹ̀ kí ó mú ẹ̀mí rẹ̀ lọ

ja[7]ku re.[8]

Àwon fiimu tí ó ti kópa

àtúnṣe
  • Àṣìṣe (1995)
  • Ilẹ̀
  • Orí
  • Ami Ayo
  • Fimi dára Ire[9]
  • Ìránṣẹ́ Ajé
  • "J J
  • Alápadúpẹ́

E tun wo

àtúnṣe
  • 4th Africa Movie Academy Awards

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe