N'Gangue M'voumbe Niambi
N'Gangue M'voumbe Niambi jẹ́ ọba ìjọba Loango ní àwọn ọdún tó gbẹ̀yìn ọdún 1600s. Ó rí ọ̀pọ̀ èrè nínú títa àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bi ẹrú fún orílẹ̀ èdè [[Kingdom of Portugal|Portugal]. Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ Olfert Dapper, Niambi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìjà ogun, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé kò mọ bí a ṣe ń lò wọ́n.