Níyì Adéolókun
Níyì Adéolókun tí wọ́n bí ní ọjọ́ Kẹ́ta oṣù Kọkànlá ọdún 1990 ( 3 November 1990) jẹ́ agbá bọ́ọ̀lù rugby fún (Irish rugby union). Ó ń gbá fún wọn gẹ́gẹ́ bí onígun (winger). Adéolókun ló tún ń gbá rugby fún ikọ̀ ( Connacht) ní Pro14. Ó dara pọ̀ mọ́ Connacht ní ọdún 2014 láti ilé-ẹ̀kọ́ 'Trinity College'. Lásìkò tí ó fi wà pẹ̀lú ilé-ẹ̀kọ́ àgbà ti (Dublin University), Ó gbá rugby sevens fún ikọ̀ ilé-ẹ̀kọ́ náà.
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí Adéolókun ní ìlú Ìbàdàn,ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Ó lọ sí ilẹ̀ Ireland pẹ̀lú àwọn òbí rẹ̀ ní ọ̀dún 2001 nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún mọ́kànlá (age 11). Ó ń ṣe oríṣiríṣi eré ìdárayá nígbà tí ó wà léwe. Ó gbá bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀-gbá fún Gaelic football àti Templeogue Synge Street tí ó sì tún gbá bọ́ọ̀lù fún League of Ireland àti Shelbourne's tí ọ̀jẹ̀-wẹ́wẹ́ tí ọjọ́ orí wọn kò ju ogún ọdún lọ (under 20).[1] Ó kọ́kọ́ gbá fún rugby union gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ ní De La Salle College ní Churchtown.[2]
Iṣẹ́ òòjọ́ rẹ̀
àtúnṣeìgbà ̀ewe rẹ̀
àtúnṣeAdéolókun gbá fún Leinster nígbà èwe rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó kúrò níbẹ̀, ó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ De La Salle tí ó jẹ́ ikọ̀ àgbà fụn ilé-ẹ̀kọ́ náà. Ní ọdún 2009, All-Ireland League nílé ìwé Dublin University bá fìwé pèé lábẹ́ àṣẹ olùdarí bọ́ọ̀lù Rugby ìyẹn Tony Smeeth. Adeólókun gbá bọ́ọ̀lù yíi fún ikọ̀ náà fún ọdún mẹ́rin. Lásìkò tí ó wà níbẹ̀, ikọ̀ nạ́à gba ife ẹ̀yẹ 'All-Ireland Championships' ní tẹ̀lé-ǹ- tẹ̀lé ní ọdún 2011 àti 2012.
Connacht
àtúnṣeNí oṣù Kárùún ọdún 2014, wọ́n kéde rẹ̀́ wípé Adéolókun fọwọ́ sí ìwé àdéhùn pẹ́̀lú (Connacht) ikọ̀ rẹ̀ tí ó wà yíi tí ó jẹ́ ọlọ́dún kan. Olùkọ́ni Nigel Carolan ni ó tọ́ka rẹ̀ fún ilé-ẹ̀kọ́ náà, lẹ́yìn tí ó ti yege nínú ìdánwò rẹ̀ ní Connacht Eagles, ní oṣù Kẹ́rin ọdún 2014.[3]
Adéolókun fakọyọ fún ikọ̀ rẹ̀ (Connacht) ní ọjọ́ Kẹfà oṣù Kẹ́sàạn ọdún 2014, nígbà tí wọ́n gbá pẹ̀lú ikọ̀ Newport Gwent Dragons nị́bi ìfẹsẹ̀-wọnsẹ̀ ìṣíde òpin ọ̀sè ní 2014–15 Pro12, níbi tí ó tí ṣe ìrànwọ́ fún akẹgbẹ́ rẹ̀ Eoin McKeon . Ọ́ tún gbá bọ́ọ̀lù àkọ́kọ́ rẹ̀ sínú àwọn lẹ́yìn ìfọwọ́ bọ̀wé rẹ̀ nị́gbà tí wọ́n gbá pẹ̀lú ikọ̀ La Rochelle níbi ìdíje 2014–15 Rugby Challenge Cup. Gbogbo bọ́ọ̀lù tí ó gbá nínú ìdíje league jẹ́ mẹsàán tí ti Challenge Cup sì jẹ́ mẹ́rin nínú ìpele ìbẹrẹ̀ ọdún.[4][5] Ní oṣù Kọkànlá ọdún 2014, wọ́n kéde rẹ̀ wípé Ó tún fọwọ́ bọ̀wé àdéhùn míìràn pẹ̀lú ikọ́̀ rè yíi Connacht láti wà pẹ̀lú ikọ̀ náà títí di òpin ọdún 2016–17.[6]
Ní 28 May 2016, (Connacht) gba ife ẹ̀yẹ àkọ́kọ́ irú rẹ̀ nị́ 2015–16 Pro12 lẹ́yìn tí wọ́n jạwé olúborí pẹ̀lú ayò 20 sí 10 tako Leinster níbi ìfẹsẹ̀-wọnsẹ̀ tó kẹ́yìn ìdịje náà. tí Adéolókun sì gbá àmì ayò náà wọlé.[7]
Ireland
àtúnṣeNovember, 2016 Adéolókun gba ìwé ìpè àkọ́kọ́ rẹ̀ láti dara pọ̀ mọ́ ikọ̀ àgba bọ́ọ̀lù àgbà fún ilẹ̀ Ireland.[8] Ó sì fakọ yọ nínú ikọ̀ náà ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Kọkànlá ọdún 2016, nígbà tí wọ́n fi rọ́pò akẹgbẹ́ rè Craig Gilroy tako ikọ̀ agbá rugby ilẹ̀ Canada.[9]
Àwọn ìtọ́ka sí
àtúnṣe- ↑ "Analysis: Connacht's sensational attack brings them Pro12 glory". The42. 29 May 2016. Retrieved 30 August 2016.
The 25-year-old has a rich sporting background in Gaelic football with Templeogue Synge Street and soccer – having played for Shelbourne’s U20 side
- ↑ "From AIL to PRO12 for speedy Adeolokun". Connacht Rugby. 12 September 2014. Archived from the original on 5 March 2016. Retrieved 11 September 2015.
- ↑ "Connacht bring in Adeolokun". Setanta Sports. 16 June 2014. Retrieved 11 September 2015.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "Connacht Squad Index: Niyi Adeolokun". Pro12. Archived from the original on 2 April 2016. Retrieved 11 September 2015.
- ↑ "Player Archive: Niyi Adeolokun". EPC Rugby. Archived from the original on 20 December 2016. Retrieved 11 September 2015.
- ↑ "Connacht extend Niyi Adeolokun contract". RTÉ Sport. 26 November 2014.
- ↑ "2016 Pro12 Final: as it happened". The 42. 28 May 2016. Retrieved 31 May 2016.
- ↑ "Jordi Murphy: Ireland flanker out for 'six to nine months' because of knee injury". BBC. 7 November 2016. https://www.bbc.co.uk/sport/rugby-union/37901414. Retrieved 7 November 2016.
- ↑ "Connacht influence strong as Schmidt's Ireland run eight tries past Canada". The42. 12 November 2016. Retrieved 12 November 2016.