Nadia Fares Anliker
Nadia Fares Anliker (tí a bí ní 18 Oṣù Kẹẹ̀sán, Ọdún 1962) jẹ́ olùdarí àti ònkọ̀tàn eré ọmọ orílẹ̀-èdè Ìjíptì àti Swítsàlandì.
Nadia Fares Anliker | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 18 Oṣù Kẹ̀sán 1962 Bern, Switzerland |
Orílẹ̀-èdè | Egyptian-Swiss |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Cairo University New York University |
Iṣẹ́ | Film director, screenwriter |
Ìgbà iṣẹ́ | 1986-present |
Ìsẹ̀mí rẹ̀
àtúnṣeA bí Fares ní ìlú Bern, orílẹ̀-èdè Swítsàlandì. Bàbá rẹ̀ jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Ìjíptì tí ìyá rẹ̀ sì jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Swítsàlandì.[1] Ó kọ́ èdè Èdè Lárúbáwá ní àkókò tí ó n kàwé ní ìlú Káírò, orílẹ̀-èdè Ìjíptì. Ó gba oyè-ẹ̀kó láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Cairo University ní ọdún 1986.[2][3] Ní ọdún yìí kan náà ni Fares ṣe adarí fíìmù fún ìgbà àkọ́kọ́ rẹ̀, àkọ́lé fíìmù náà n ṣe Magic Binoculars. Fares bẹ̀rẹ̀ sí ní lọ ilé-ẹ̀kọ́ gíga New York University ní ọdún 1987 láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa fíìmù. Ní ọdún 1991, ó gba ẹ̀bùn kan tí ààjọ Stanley Thomas Johnson Foundation gbé kalẹ̀ nípasẹ̀ fíìmù oníṣókí rẹ̀ kan táa pe àkọ́lé rẹ̀ ní Sugarblues. Ní àkókò tí ó wà ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga New York University, Fares ṣe amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ fún Krzysztof Kieślowski níbi àwọn fíìmù tí ó darí.[4] Fares padà tún gba oyè-ẹ̀kọ́ gíga nínu ìmọ̀ fíìmù ní ọdún 1995.[5]
Ní ọdún 1996, Fares darí àkọ́kọ́ fíìmù gígùn tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Miel et Cendres. Fíìmù náà dá lóri àwọn mẹ́ta kan tí wọ́n ń ti ìlú kan bọ́ sí òmíì.[6] Lápapọ̀, fíìmù náà ti gba àmì-ẹ̀yẹ méjìdínlógún níbi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ayẹyẹ àjọ̀dún fíìmù, tó fi mọ́ ti ẹ̀bùn Oumarou Ganda, èyí tí ó gbà níbi ayẹyẹ Panafrican Film and Television Festival of Ouagadougou.[7][8] Fares ti darí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn fíìmù tó dá lóri àwùjọ àti òṣèlú fún ilé-iṣẹ́ RTS/TV5 Monde.[9]
Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀
àtúnṣe- 1986 : Magic Binoculars (short film)
- 1986 : Letters from New York (short film)
- 1987 : Projections on Sundays (short film)
- 1987 : Semi-Sweet (short film)
- 1988 : Charlotte's Empire (short film)
- 1988 : 1001 American Nights (short film)
- 1990 : Sugarblues (short film)
- 1992 : D'amour et d'eau fraîche (short film)
- 1993 : Made in Love (short film)
- 1995 : Portrait d'une femme séropositive (short film)
- 1995 : Lorsque mon heure viendra (short film)
- 1996 : Miel et Cendres
- 2003 : Anomalies passagères (TV film)
- 2011 ; Expectations
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Hillauer, Rebecca (2005). Encyclopedia of Arab Women Filmmakers. American Univ in Cairo Press. p. 66. ISBN 978-9-774-24943-3.
- ↑ Hillauer, Rebecca (2005). Encyclopedia of Arab Women Filmmakers. American Univ in Cairo Press. p. 66. ISBN 978-9-774-24943-3.
- ↑ "Honey and Ashes". African Film Festival New York. Retrieved October 8, 2020.
- ↑ Encyclopedia of Arab Women Filmmakers.
- ↑ "Honey and Ashes". African Film Festival New York. Retrieved October 8, 2020.
- ↑ "Honey and Ashes". African Film Festival New York. Retrieved October 8, 2020.
- ↑ "Honey and Ashes". African Film Festival New York. Retrieved October 8, 2020.
- ↑ Barlet, Olivier (24 September 2002). "Fespaco 1997 : le développement sera culturel ou ne sera pas". Africultures. Retrieved 8 October 2020.
- ↑ "Honey and Ashes". African Film Festival New York. Retrieved October 8, 2020.