Nafisat Abdullahi


Nafisat Abdulrahman Abdullah tí ó gbajúmò gẹ́gẹ́ bíi Nafisat Abdullahi(tí a bí ní ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kìíní ọdún 1992) jẹ́ òṣèré, adarí eré, ayàwòrán àti oníṣòwò láti ìlú Jos ní ìpínlẹ̀ Plateau. Ó ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì ẹ̀yẹ, lára wọn sì ni Afro Hollywood Award(2017), MTN award(2016), AMMA Award(2015) àti City People Entertainment Award ní ọdún 2013 gẹ́gẹ́ bí òṣèré bìnrin tó dára jù lọ àti Kannywood Award in 2014. Ó bẹ̀rẹ̀ eré ṣíṣe nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún méjìdínlógún níbi tí ó ti kópa nínú eré Sai Wata Rana ní ọdún 2010.