Natasha Bowen jẹ́ olùkọ́ àti òǹkọ̀wé ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà-tó tan-mọ́-àwọn-ará-Wales. Ó ń kọ àwọn ìwé aláìdálérí-ìtàn-gidi fún àwọn ọ̀dọ́.[1][2] Wọ́n mọ̀ ọ́n fún ìwé ìtàn-àròsọ rẹ̀ Skin of the Sea, tó jẹ́ ìwé ìtàn-àròsọ tó ń tà jù ní New York.[3][4]

Natasha Bowen
Ọjọ́ ìbíCambridge, England
Iṣẹ́Writer, teacher
Ọmọ orílẹ̀-èdèNigerian
Welsh
Ẹ̀kọ́Bath Spa University
Ìgbà 2020–present
GenreFantasy, Young Adult
Notable worksSkin of the Sea
Website
natashabowen.com

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí Natasha Bowen sí Cambridge, ní England, sí bàbá tó jẹ́ ọmọ Yorùbá àti si ìyá tó jẹ́ ọmọ Wales. Ó dàgbà ní Cambridge pẹ̀lú ìṣínilójú sí àṣà Yorùbá, èyí tó padá̀ lò nínú àwọn àkọsílẹ̀ rẹ̀.[5][6] Ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Creative Writing ní Bath Spa University. Léyìn tó kẹ́kọ̀ọ́ jáde, ó kó lọ sí apá Ìlà-oòrùn London, níbi tí ó ti di olùkọ́.

Iṣẹ́ tó yàn láàyò

àtúnṣe

Ìwé àkọ́kọ́ Bowen ni Skin of the Sea, èyí tó jẹ́ ìwé àkọ́kọ́ ti Of Mermaid and Orisa series, èyí tó jẹ́ èrò àtinúdá rẹ̀ látara àṣà Yorùbá tó ti kọ́, ìyẹn nípa ìtàn-àròsọ ti ilẹ̀ Afrika, àṣà Yorùbá, àti ìfẹ́ rẹ̀ fún Yemọja. Ó tẹ ìwé yìí jáde ní 2 November 2021 láti ọwọ́ ilé-iṣẹ́ atẹ̀wétà ti Random House. Ó kọ ìwé náà lásìkò tí ó jẹ́ olùkọ́ ní ilé-ìwé.[7][8]

Lẹ́yìn náà ló kọ Simi, tó jẹ́ ìtàn nípa Mami Wata tó rin ìrìn-àjò lọ sí òkè-òkun láti lọ ṣàwárí Ẹlẹ́dàá lẹ́yìn tí ó rú ọ̀fin tó tako ìwàláyé àwọn Mami Wata. Ìwé náà wọ orí New York Times[9] àti Indie bestseller lists, ó sì gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àríwísí tó dáa, àwọn òǹkàwé náà sì yin òǹkọ̀wé fún ìjọra ìwé náà pẹ̀lú The Little Mermaid àti ìlò Yemọjà ti ilẹ̀ Adúláwọ̀ àti àṣà Yorùbá láti fi ṣàfihàn Transatlantic Slave Trade.[10][11][12]

Soul of the Deep ni ìwé tó kọ lẹ́yìn náà, ó sì jáde ní September 27, 2022.[13][14]

Àtòjọ ìwé rẹ̀

àtúnṣe

Of Mermaid and Orisa Series

  • Skin of the Sea. (November 2, 2021) Random House
  • Soul of the Deep. (forthcoming, 2022) Random House

Àwọn ìtókasí

àtúnṣe
  1. "Natasha Bowen". Penguin Random House (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-11-11. 
  2. "Q&A With Natasha Bowen, Skin of the Sea". We Need Diverse Books (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-11-05. Retrieved 2021-11-11. 
  3. "SKin of the Sea by Natasha Bowen" (in en-US). The New York Times. ISSN 0362-4331. https://www.nytimes.com/books/best-sellers/young-adult-hardcover/. 
  4. Harlan, Jennifer (2021-11-09). "4 New Y.A. Fantasy Novels Full of Dark, Enchanting Twists" (in en-US). The New York Times. ISSN 0362-4331. https://www.nytimes.com/2021/11/09/books/review/year-of-the-reaper-beasts-of-prey-skin-of-the-sea-gilded.html. 
  5. "An Indies Introduce Q&A With Natasha Bowen". American Booksellers Association. 2021-10-22. Retrieved 2021-11-11. 
  6. Eddy, Cheryl (26 October 2021). "A Mermaid Tests Her Fate in West African-Inspired Tale Skin of the Sea". Gizmodo (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-11-11. 
  7. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named :12
  8. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named :22
  9. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named :32
  10. Paxson, Caitlyn (2021-10-28). "'Skin of the Sea' sends its little mermaid swimming into very different waters" (in en). NPR. https://www.npr.org/2021/10/28/1049805130/skin-of-the-sea-natasha-bowen-review. 
  11. "Children's Book Review: Skin of the Sea by Natasha Bowen.". Publishers Weekly (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 23 September 2021. Retrieved 2021-11-11. 
  12. "SKIN OF THE SEA". Kirkus Reviews. September 15, 2021. 
  13. "Skin of the Sea Mermaid Fantasy Sequel First Look Natasha Bowen". gizmodo.com. Retrieved 2022-05-08. 
  14. "Soul of the Deep by Natasha Bowen: 9780593120989 | PenguinRandomHouse.com: Books". PenguinRandomhouse.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-05-08.