Ngardy Conteh George (tí a bí ní ọdún 1979) jẹ́ olùdarí eré àti olóòtú ọmọ orílẹ̀-èdè Siẹrra Léónè àti Kánádà

Ngardy Conteh George
Ọjọ́ìbíNgardy Conteh
Freetown, Sierra Leone
Orílẹ̀-èdèSierra Leonean-Canadian
Iléẹ̀kọ́ gígaUniversity of New Orleans
Iṣẹ́Film director, film producer, editor
Ìgbà iṣẹ́2004-present
Olólùfẹ́Philman George
Àwọn ọmọ2

Ìsẹ̀mí rẹ̀

àtúnṣe

Ìlú Freetown ni wọ́n bí George sí, ṣùgbọ́n ó lọ sí ìlú Kánádà ní àsìkò ìgbà èwe rẹ̀. Ó lọ sí Yunifásitì ìlú New Orleans pẹ̀lú owó-ìrànlọ́wọ́ ìwé kíkà.[1] Lẹ́hìn ìparí ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó gbájúmọ́ iṣé fíìmù ṣíṣe tó sì n sọ àwọn ìtàn nípa fífọ́nká àwọn ọmọ ilẹ̀ Áfríkà.[2] Ní ọdún 2004, ó ṣe adarí fíìmù fún ìgbà àkọ́kọ́ rẹ̀ nígbà tí ó fi dári eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Soldiers for the Streets, èyí tí n ṣàlàyé nípa akitiyan Ras King láti kọ́ àwọn ọ̀dọ́ lẹ́kọ̀ọ́.[3] Ó ṣe adarí eré oníìrírí tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Literature Alive ní ọdún 2005. Yàtọ̀ sí ṣíṣe adarí eré, George tún ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi olóòtú fún àwọn eré bíi I Want to Be a Desi (apà kejì), Something Beautiful, Arts & Minds, Food & Drink TV àti The Marilyn Denis Show fún ìkànnì CTV.[4] Láti ilé-iṣẹ́ rẹ̀ tí ó pè ní Mattru Media, ó ṣe àgbékalẹ̀ ètò tẹlifíṣọ̀nù kan tí a pè ní The Rhyming Chef Barbuda.[5]

Ní ọdún 2008, ó darí eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ The Circle of Slavery pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ní Siẹrra Léónè. Eré náà dá lóri àwọn ìbátan àtijọ́ tí ó wà láàrin orílẹ̀-èdè Siẹrra Léónè ati Kánádà.[6] Ní ọdún 2014, George darí eré The Flying Stars pẹ̀lú owó tí Sundance Documentary Film Fund gbé kalẹ̀. Eré náà gba àmì-ẹ̀yẹ eré ìrírí tí ó dára jùlọ níbi ayẹyẹ BronzeLens Film Festival ti ọdún 2015.[7]

Àwọn àṣàyàn eré rẹ̀

àtúnṣe
  • Soldiers for the Streets (2004)
  • Literature Alive (2005)
  • The Circle of Slavery (2008)
  • The Rhyming Chef Barbuda (2009)
  • The Flying Stars (2014)
  • Dudley Speaks for Me (2016)
  • Mr. Jane and Finch (2019)

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Ngardy Conteh George" (PDF). CIBWE. Retrieved 12 October 2020. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  2. "Ngardy Conteh George - Biography". African Film Festival New York. Retrieved 11 October 2020. 
  3. "Soldiers for the Streets". National Film Board of Canada. 15 August 2017. Archived from the original on 30 November 2021. Retrieved 11 October 2020. 
  4. "Ngardy Conteh George - Biography". African Film Festival New York. Retrieved 11 October 2020. 
  5. "OYA Media Group on Canadian Screen Awards Win, Mr. Jane and Finch, and Future Plans". Enspire. 3 August 2020. Retrieved 11 October 2020. 
  6. "Ngardy Conteh George" (PDF). CIBWE. Retrieved 12 October 2020. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  7. "Ngardy Conteh George". Canadian Film Centre. Archived from the original on 30 November 2021. Retrieved 11 October 2020. 

Àwọn ìtakùn Ìjásóde

àtúnṣe