Ngozi Ezeonu
Ngozi Ezeonu tí orúkọ àbísọ rẹ̀ ń jẹ́ Ngozi Ikpelue ni wọ́n bí ní Ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù karùn-ún ọdún 1965 (May 23rd 1965) jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin sinimá àgbéléwò àti akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ òníròyìn tẹ́lẹ̀ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin ìlúmọ̀ọ́kà nípa ṣíṣe ẹ̀dá-ìtàn Ìyá nínú sinimá àgbéléwò lédè Gẹ̀ẹ́sì àti Ìgbò. [1][2][3] Lọ́dún 2012, ó kópa nínú sinimá àgbéléwò kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Adesuwa, èyí ló mú un gba àmìn ẹ̀yẹ Akádẹ́mì nínú sinimá gẹ́gẹ́ bí òṣèrébìnrin tó dára jùlọ níbi ayẹyẹ igbàmìẹ̀ẹ ẹlẹ́ẹ̀kẹjọ 8th Africa Movie Academy Awards.
Ngozi Ezeonu | |
---|---|
Ngozi Ezeonu In "Family Secret", 2016 | |
Ọjọ́ìbí | Ngozi Ikpelue Ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù karùn-ún ọdún 1965 ìlú Owerri |
Orílẹ̀-èdè | Ọmọ Nàìjíríà |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Nigerian Institute of Journalism |
Iṣẹ́ | Òṣèrébìnrin |
Ìgbà èwe rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí ní Ngozi Ezeonu ní ìlú Owerri. Kí ó tó di gbajúmọ̀ òṣèré ìlúmọ̀ọ́kà, ó kàwé gbàwé ẹ̀rí nínú ìmọ̀ iṣẹ́ ìròyìn ní Nigerian Institute of Journalism, ó sìn ṣiṣẹ́ ní Radio Lagos àti Eko FM.[4]
Aáyan rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣèré sinimá àgbéléwò
àtúnṣeBí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó gbajúmọ̀ gẹ́gẹ́ bí kíkópa ẹ̀dá-ìtàn ìyá, ó ti kọ́kọ́ kópa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá-ìtàn ọlọ́mọgé ní ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíátà rẹ̀ ṣíṣe. Lọ́dún 1993, ni gbajúgbajà olùdarí sinimá-àgbéléwò nì, Zeb Ejiro fún ní ipa amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀dá-ìtàn, tí ó pè ní Nkechi nínú sinimá àgbéléwò kan lédè Ìgbò, tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Nneka The Pretty Serpent. Lẹ́yìn èyí, ó kópa nínú sinimá àgbéléwò mìíràn tí wọ́n pe àkọ́lé rẹ̀ ní Glamour Girls lọ́dún 1994, ó kópa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá-ìtàn tí wọ́n pè ní .[5]
Àtòjọ díẹ̀ lára àwọn sinimá-àgbéléwò rẹ̀
àtúnṣeNgozi tí kópa nínú sinimá àgbéléwò tí ó ju àádọ́jọ lọ, lára wọn ni;
- Glamour Girls
- Shattered Mirror
- The Pretty Serpent
- Tears of a Prince
- Cry of a Virgin
- Abuja Top Ladies
- Family Secret
- The Confessor
- The Kings and Gods
- Zenith of Sacrifice
- A Drop of Blood
- Divided Kingdom
- Diamond Kingdom
- God of Justice
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Sudden weight loss: ‘I am not sick,’ cries Ngozi Ezeonu". vanguardngr.com. Retrieved 21 August 2014.
- ↑ "As Nollywood prepares for its first ever movie awards, ace Nigerian actress; Ngozi Ezeonu, reminisces about the industry". TheAfricanDream.net. Retrieved 4 December 2019.
- ↑ "Ngozi Ezeonu Biography". gistus.com. Retrieved 21 August 2014.
- ↑ Ngozi Ezeonu: I Was a Journalist Before I Became an Actress
- ↑ Throwback Glamour Girls