Ngozi Nwozor-Agbo /θj/ (ọjọ́ 21 oṣù kẹfà, ọdún 1974 sí ọjọ́ 28 oṣù karùn-ún, ọdún 2012) jẹ́ oníròyìn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà,[1] òǹkọ̀wé àti akéwì tí gbogbo ènìyàn ń pè ní ‘Lady Campus’. Ó jẹ́ ìlú mọ̀ọ́ká ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà gẹ́gẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tí ó dá ìwé-ìròyìn ọgbà Fáṣítì sílẹ̀ tí ó pè ní ìgbésí ayé ọgbà Fáṣítì (CampusLife), èyí tí ó jẹ jáde látinú àwọn ìwé-ìròyìn The Nation fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti inú ọgbà Fáṣítì jákèjádò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó tún jẹ́ gbajúgbajà nípa kíkọ ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀dọ́ tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti di àwọn òǹkọ̀ròyìn tí ó gbámúṣẹ́.[2][3]

Ngozi Nwozor
Ọjọ́ìbíJune 21, 1974 (1974-06-21)
Onitsha, Anambra, Nigeria
AláìsíÀsìṣe ìgbéọ̀rọ̀sílẹ̀: Àìdámọ̀ àmì ìdádúró-ọ̀rọ̀ sókí "{"., May 28, 2012 (ọmọ ọdún Àsìṣe ìgbéọ̀rọ̀sílẹ̀: Àìdámọ̀ ọ̀rọ̀ "may".)
Lagos
Ẹ̀kọ́Yunifásítì ti Nàìjíríà
Yunifásitì ìlú Èkó
Iṣẹ́Journalist
OrganizationThe Nation (Nigeria) Newspapers
Gbajúmọ̀ fúnCampusLife

Ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé àti iṣẹ́ àyànṣe

àtúnṣe

Wọ́n bí Ngozi Agbo ní ìlú Onitsha, ní ìpínlẹ̀ Anambra, ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó lọ sí Fáṣítì tí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Nsukka (UNN), níbi tí ó ti kọ́ ẹ̀kọ́ ìmọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ó jẹ́ ajàfẹ́tọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ó múnádóko wọ́n sì yàn-án gẹ́gẹ́ bí igbákejì Ààrẹ ti ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tí ìjọba ti UNN ní ọdún 1999. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè Másítà nínú ìmọ̀-ẹ̀kọ́ ìtàn àti ẹ̀kọ́-ìmọ̀ ìbáṣepọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè ní Fáṣítì Èkó (UNILAG). Ngozi darapọ̀ mọ́ ìwé-ìròyìn The Nation ní ọdún 2007, pẹ̀lú pé ó ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìwé-ìròyìn New Age àti àwọn àjọ tí kìí ṣe ti Ìjọba (NGO), Fate Foundation.

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "USA/Africa Dialogue, No 403: Nelson Mandela Institute". 
  2. "Ngozi Agbo: The unforgettable impact". 27 May 2015. 
  3. https://www.pmnewsnigeria.com/2010/05/21/all-hail-campus-life-spoils-students-at-writers%E2%80%99-workshop/