Oluwakemi Nina Sosanya (bíi ni ọjọ́ kẹfà oṣù kẹfà ọdún 1969) jẹ́ òṣèré tí ó gbajúmọ̀ fún ipa tí ó kó nínú eré W1A àti Last Tango in Halifax.[1][2]

Nina Sosanya
Ọjọ́ìbíOluwakemi Nina Sosanya
6 Oṣù Kẹfà 1969 (1969-06-06) (ọmọ ọdún 54)
Islington, London, England
Iṣẹ́Actress
Ìgbà iṣẹ́1992–present

Ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ àtúnṣe

Wọ́n bí Sosanya sí ìlú Islington ní London. Baba rẹ̀ jẹ́ ọmọ ìpínlẹ̀ Nàìjíríà, ìyá rẹ sí jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Britain. Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Vale of Catmose College ní Oakham.[3]

Iṣẹ́ àtúnṣe

Sosanya tí kópa nínú orísìírísìí eré orí ìtàgé, fíìmù àti eré orí tẹlẹfíṣọ̀nù. Eré orí ìtàgé tí ó kọ́kọ́ fi di gbajúmọ̀ ni eré Anthony and Cleopatra àti eré Teachers tí wọ́n ṣe ní ọdún 2001[4]. Ó ti kopa ninu awọn eré bíi Sorted, People Like Us, Make me Famous[5], Love Actually, Nathan Barley, The vote[6], Renaissance, Casanova,The Three Gamblers, Much Ado About Nothing, Cape Wrath/Meadowlands, the Doctor Who episode Fear Her, àti FM.[7] Ní ọdún 2003, ó kó ipa Rosalind nínú eré As You Like It. Ní ọdún, ó kó ipa Rosaline nínú eré Love's Labour's Lost. Ní ọdún 2016, ó farahàn nínú eré Young Chekhov, ó sì kó ipa Laura Porter nínú eré Marcella.[8]

Àwọn Ìtọ́kàsi àtúnṣe