Nkoyo Esu Toyo (ti a bi ni ọjọ́ Kàrún oṣù kọkànlá ọdún 1958) jé agbejoro, ajafun idagbasoke, ati òtòkùlú oloselu ní orílè-èdè Nàìjirià. A diboyan si ilé igbimo asofin láti se Aṣojú ekùn Calabar-Odukpani ti ìpinlè Cross Rivers, Nàìjíríà ní odun 2011,[1] kó tó dipe o darapo mó ilé igbimo asofin, o jé aṣojú Nàìjirià sí orílè-èdè Ethiopia àti Djibouti titi di 2010. Ṣaaju kí o tó wo oṣelu, o se ajoda Gender and Development Action (GADA) ni 1991, egbé tí a dá kalè láti ran àwon obinrin lówó lati ní ètó sí nkan oselu àti ètò-orò. [2] Nkoyo Toyo jé ọmọ-ẹgbẹ́ oríṣiríṣi ẹgbẹ́ tí óún jà fun ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin ní àgbáyé.[3]

Èkó rè

àtúnṣe

Nkoyo pari iwe Sekondiri rè ní Union Secondary School ní odun 1974, ó si tesiwaju lati ko nipa ìmò ofin ni Ahmadu Bello University, Zaria Kaduna ni 1975. Ni 1980 Nkoyo Toyo jade ni Nigerian Law School a sì pé sí Nigerian Bar Association. Lẹhinna o gba oye Master of Laws (LLM) lati Yunifásitì ilu Lagos ni ọdun 1994.[4] Nitori itara ati iṣẹ rẹ ni ríran awọn obinrin lówó, a fun ní Sikolashipu Chevening lati kawe ni Institute of Development Studies (IDS), University of Sussex, nibiti o ti gba Masters in Governance ni odun 2001.

Òsèlú

àtúnṣe

A yàn Nkoyo láti jé asojú Nàìjirià sí orílè-èdè Ethiopia àti Djibouti ní odun 2008 nitori Ife rè sí oselu. Ni odun 2011, lábé oselu People's Democratic Party (PDP), a yan Nkoyo sí ilé ìgbìmò asojú láti se asojú ekùn Calabar-Odukpani ti ipinle Cross Rivers, o sì sisé takuntakun lórí idagbasoke àwùjo.

Àwon Itokasi

àtúnṣe
  1. "Good governance: How civil society is missing it - Rep Nkoyo Toyo". Vanguard News. 2012-08-13. Retrieved 2022-05-23. 
  2. "Nigeria has too many laws already - Hon. Nkoyo Toyo". Vanguard News. 2013-08-24. Retrieved 2022-05-23. 
  3. Cornwall, A.; Molyneux, M. (2013). The Politics of Rights: Dilemmas for Feminist Praxis. ThirdWorlds. Taylor & Francis. p. 12. ISBN 978-1-317-99675-0. https://books.google.com/books?id=WWXdAAAAQBAJ&pg=PA12. Retrieved 2022-05-23. 
  4. "Nkoyo Toyo (Politician) Wiki, Biography, Age, Husband, Family, Net Worth". Wiki: Biography & Celebrity Profiles as wikipedia. 2021-10-27. Retrieved 2022-05-23. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]