Nnamdi Kanu jẹ́ ajìjàǹgbara ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Bìrìtìkó. Òun ni olùdásílẹ̀ àti adarí ẹgbẹ́ ajìjàǹgbara Indigenous People of Biafra (IPOB).[1] Ẹgbẹ́ yìí ló ń jìjàǹgbara òmìnira àti ìdásílè orílè-èdè Biafra . Nnamdi Kanu náà olùdásílẹ̀ ilé-ìṣe rédíò kan tí a mọ̀ sí Radio Biafra tó wà lórílẹ̀-èdè Bìrìtìkó. Ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fi ṣìnkún òfin ìfipá-dàjọba-bolẹ̀ mú un ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹwàá ọdún 2015, wọ́n sì tì í mọ́lé fún ìgbà pípé bí ó tilè jẹ́ pé ọ́pọ̀ ilé-ẹjọ́ dájọ́ pé kí Wọ́n dá a sílẹ̀. Nígbà tí Kanu ń farahàn nílé ẹjọ́, ìṣe ló máa ń múra bíi ọmọ Júù. Ó sọ nílé-ejò pé òun nígbàgbọ́ nínú ẹ̀sìn àwọn Júù, òun sì ń rí ara òun gẹ́gẹ́ bíi ọmọ Júù. Ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà dá a sílè lọ́jọ́ kejìdínlógún oṣù kẹrin ọdún 2017 pẹ̀lú béèlì pé kò gbọ́dọ̀ fi orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sílè, ṣùgbọ́n ó sá lọ gba ọ̀nà ẹ̀bùrú sí òkè-òkun.[2][3]

Nnamdi Kanu

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "About Nnamdi Kanu - Nnamdi Kanu Background". LATEST NIGERIAN NEWS BREAKING HEADLINES NEWSPAPERS. 2017-01-25. Retrieved 2019-10-06. 
  2. "Court orders arrest of Nnamdi Kanu, revokes bail -". Premium Times Nigeria. 2019-03-28. Retrieved 2019-10-06. 
  3. "Nnamdi Kanu". The Independent. 2018-11-30. Retrieved 2019-10-07.