Noufissa Benchehida
Noufissa Benchehida (tí wọ́n bí ní 23 Oṣù Kẹẹ̀wá Ọdún 1975) jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Mòrókò.
Noufissa Benchehida | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 23 Oṣù Kẹ̀wá 1975 |
Orílẹ̀-èdè | Moroccan |
Iṣẹ́ | Actress |
Ìgbà iṣẹ́ | 2004-present |
Ìsẹ̀mí rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí Benchehida ní Mòrókò ní ọdún 1975. Ó fẹ́ràn eré sinimá láti ìgbà èwe rẹ̀.[1] Ó kẹ́kọ̀ọ́ ní ilé-ìwé Cours Florent tí ó wà ní ìlú Paris. Benchehida gba oyè-ẹ̀kọ́ nínu ìmọ́ eré-ìtàgé láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Conservatory of Casablanca,[2] bẹ́ẹ̀ ló sì tún lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Ecole supérieure d'hôtellerie et de tourisme à Montpellier.[3]
Benchehida kó àkọ́kọ́ ipa fíìmù rẹ̀ ní ọdún 2004 nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Syriana tí olùdarí rẹ̀ síì n ṣe Stephane Cagan.[4] Ó di gbajúmọ̀ lẹ́hìn tí ó kó ipa Zineb Hejjami gẹ́gẹ́ bi ọlọ́pàá nínu eré tẹlifíṣọ̀nù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ El kadia ní ọdún 2006. Ó sọ di mímọ̀ wípé òun gbádùn kíkó ipa náà ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ láti máa ṣe irúfẹ̀ ipa bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ìgbà, àti pé òun fẹ́ láti kópa nínu àwọn eré oníjà.[5] Bákan náà ní ọdún 2006, ó kópa nínu eré tẹlifíṣọ̀nù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Moulouk Attawaif. Ní ọdún 2011, Benchehida kó ipa olú-ẹ̀dá-ìtàn nínu eré Agadir Bombay, gẹ́gẹ́ bi obìnrin kan tí ó n ṣe àgbàwí fún àwọn obìnrin ẹgbẹ́ rẹ̀. Myriam Bakir ló darí eré náà.[6] Ní ọdún 2015, ó kópa nínu fíìmù Aida.
Ní ọdún 2016, Benchehida kópa nínu eré tí àkólẹ́ rẹ̀ jẹ́ A la recherche du pouvoir perdu ("Ṣíṣe àwárí agbára tí ó sọnù"), èyí tí Mohammed Ahed Bensouda darí. Iṣé takuntakun rẹ̀ nínu eré náà ló fun ńi àmì-ẹ̀yẹ ti Golden Sotigui níbi ayẹyẹ Sotigui Awards ti ọdún 2017.[7] Benchehida tún gba àmì-ẹ̀yẹ òṣèrébìnrin tí ó dára jùlọ níbi ayẹyẹ Panafrican Film and Television Festival of Ouagadougou.[8]
Benchehida maá n sọ èdè Faransé, èdè Lárúbáwá àti èdè Gẹ̀ẹ́sì.[9]
Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀
àtúnṣe- 2004 : Syriana
- 2006 : El kadia (TV series)
- 2006 : Moulouk Attawaif (TV series)
- 2009 : Elle
- 2010 : Scars (short film)
- 2010 : Une heure en enfer (TV series)
- 2011 : Agadir Bombay
- 2013 : Beb El Fella - Le Cinemonde
- 2013 : Appel Forcé
- 2015 : Aida
- 2016 : Massafat Mile Bihidayi
- 2016 : A la recherche du pouvoir perdu
- 2018 : Wala alik (TV series)
- 2020 : Alopsy (short film)
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Zerrour, Leila. "Benchehida Noufissa : «Je ne suis pas seulement une femme flic»". Maghress (in French). Retrieved 7 November 2020.
- ↑ "Noufissa Benchehida". Agenzia Isabella Gullo (in French). Retrieved 7 November 2020.
- ↑ "Retour de Noufissa Benchida au cinéma : Rôle principal dans le film “Agadir-Bombay”". Liberation (in French). Retrieved 7 November 2020.
- ↑ "Noufissa Benchehida". Agenzia Isabella Gullo (in French). Retrieved 7 November 2020.
- ↑ Zerrour, Leila. "Benchehida Noufissa : «Je ne suis pas seulement une femme flic»". Maghress (in French). Retrieved 7 November 2020.
- ↑ "Retour de Noufissa Benchida au cinéma : Rôle principal dans le film “Agadir-Bombay”". Liberation (in French). Retrieved 7 November 2020.
- ↑ "Moroccan actress Noufissa Benchehida wins Golden Sotigui". Moroccan Ladies.com. 2017. Archived from the original on 17 November 2021. Retrieved 7 November 2020.
- ↑ Grira, Mohamed (5 March 2017). "Fespaco 2017: L'Étalon d'or revient à Alain Gomis pour son film "Félicité"". Anadolu Agency (in French). Retrieved 7 November 2020.
- ↑ "Noufissa Benchehida". Agenzia Isabella Gullo (in French). Retrieved 7 November 2020.