Oògùn Àjẹsára
Oògùn àjẹsára tàbí Abẹ́rẹ́ Àjẹsára jẹ́ agbo kan tí a ṣe láti fúni ní ààbò tó péye kúrò lọ́wọ́kòkòrò , àrùn ati àìsàn tí ó fẹ́ wọlé sí agọ́ ara. Àwọn ohun tí wọ́n fi ńnṣe oògùn abẹ́rẹ́ àjẹsára yí ni díẹ̀ lára àwọn légbé-n-légbé tí ó lágbára jùlọ àmọ́ tí kò ní agbára mọ́ ní asìkò tí wọ́n fẹ́ ṣamúlò rẹ̀ tàbí kí wọ́n kúkú pa légbé-n-légbé yí ṣáájú kí wọ́n tó ṣamúlò rẹ̀.[1] Àwọn légbé-n-légbé tí wọ́n ṣamúlò yí ni wọ́n yóò lò láti fi ṣe láti fi kún àwọn èròja mìíran tí yóò sì ma ṣiṣẹ́ ìdẹ́rùba fú èyíkéyí àìsàn àti àrùn tí ó fẹ́ fipá wọ inú àgọ́ ara ènìyàn tàbí ẹranko Fífún ènìyàn kan ní oògùn àjẹsára ni ìgbésẹ̀ tí a ń pè ní "gbígba abẹ́rẹ́ àjẹsára". Lára àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára tí wọ́n múná dóko ni abẹ́rẹ́ àjẹsára fún àrùn rọpá-rosẹ̀, àìsàn òtútù ìta, òtútù àyà àrùn HPV àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ọ̀gbẹ́ni Edward Jenner ni ó ṣe ìdásílẹ̀ gbólóhùn "abẹ́rẹ́ àjẹsára ati gbígba abẹ́rẹ́ àjẹsára " ni wọ́n fàyọ láti inú ọ̀rọ̀ (Veriolae).[2]
Ìmúnádóko àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára
àtúnṣeGbígba abẹrẹ ajẹsara jẹ́ ohun tí kò léwu tí kò sì mú ìpalára dání láti fi kojú àrùn kárùn tàbí àìsàn èyíkéyí. Síbẹ agbára àwọn abẹ́rẹ àjẹsára yí ní àkùdé, bákan náà ni agbaára wọn gbára lé àwọn nka mélòó kan. Lára wọn ni: Àìsàn náà fúnra rẹ̀, ( abẹ́rẹ́ àjẹsára lè má ṣiṣẹ́ nígbà tí a bá gbàá fún àrùn tàbí àìsàn tí kò bá mu). [3] Bí wọ́n bá ń ṣe iṣẹ́ ìwádí lọ́wọ́ (àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára tí wọ́n ti pèsè sí lè má bá àrùn kan tabí òmíràn tí wọ́n ń ṣe ìwádí rẹ̀ lọ́wọ́). Títẹpẹlẹ mọ́ ìgba abẹ́rẹ́ àjẹsára lóòrè kóòrè fún àrùn tàbí àisàn kan, kódà bí àrùn bá ti kásẹ̀ nílẹ̀ tán pátá. Bí won tẹle iṣeto gbigba abẹrẹ ajẹsara daradara. Àdámọ́ ara ẹnì kòọ̀kan. Abẹ́rẹ́ àjẹsára tún lè má ṣiṣẹ́ lára àwọn ènìyàn kan tàbí òmíràn látàrí àdámọ́ ara kálukú. Àwọn okùnfà míràn tún ni "ọjọ́-orí, ẹ̀yà ati àbùdá ara tí wọ́n ń pè ní (jẹ̀nẹ́tíìkì) àti bèé bẹ́ẹ̀ lọ.[4]
Bí ẹni tí a fún ní abẹ́rẹ́ àjẹsára bá sì tún lùgbàdì àìsàn tàbí àrùn tí wọ́n torí rẹ̀ fun ní abẹ́rẹ́ fun , ó dájú wípé àìsàn náà kò ní gbilẹ̀ lára onítòhún tó ẹni tí kò gba abẹ́rẹ́ àjẹsára rárá. [5]
Àwọn akíyèsí wọ̀nyí ṣe pàtàkì nípa fífi ìmúná-dóko oògùn àjẹsára nínú ètò ìfúni lábẹ́rẹ́ àjẹsára. Gbígbé ìlànà ìtọpinpin sí ìmúná-dóko iṣẹ́abẹ́rẹ́ àjẹsára lára àwọn ènìyàn nígbà tí a bá ti fún wọ n gègẹ́ bí a ṣe ṣàláyé ré nínú ìpolongo wa gbogbo. Ìfojúsóde fún àwọn àrùn míran tó bá tún ṣẹ́ yọ lásìkò ìfúni ní abẹ́rẹ́ àjẹsára. Mí ma ṣe ìmúlò ìfúni ní abèrẹ́ àjẹsára lóòrè kóòrè, kódà bí àrùn bá kásẹ̀ nílẹ̀ tán.
Ṣíṣàmúlò oògùn àjẹsára ma ń mú kí àdínkù tàbí kí àjakálẹ̀ àrùn èyíkéyí ó kásẹ̀ nílẹ̀ tán pátá pátá. Pàá pàá jùlọ, àwọn àjàkálẹ̀ àrùn bíi ìgbóná, rọpá-rọsẹ̀, òtútù ìta, rùbẹ́là, àìsàn ibà pọ́njú-pọ́ntọ̀ àti vẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ti di ohun afìsẹ́yìn, yàtọ̀ sí bí wọ́n ṣe pọ̀ jántì-rẹrẹ ní nkan bí ọgọ́rùún ọdún sẹ́yìn Bí ọ̀gọ̀rọ̀ ènìyàn bá gba abẹrẹ àjẹsára, yóò nira púpọ̀ fún àìsàn kan láti bẹ́ sílẹ̀tàbí di ìtànkálẹ̀kiri. Ìgbésẹ̀ yí ni a ń pè ní àjẹsára tó gbópọn. Àwọn oògùn àjẹsára tún ma ń ṣe ìrànwọ́ fún ìdènà ìdàgbà-sókè àti ìgbèrú agbára àwọn kòkòrò tí wọ́n ma ń pa oògùn apa kòkòrò nínú ara. Fún àpẹrẹ, mímú àdínkù bá ìṣẹ̀lẹ̀ àìsàn òtútù àyà tí Streptococcus pneumonia máa ń ṣokùnfà rẹ̀, àwọn ètò ìfúni labẹ́rẹ́ ajẹsara lóríṣríṣi ti mú àdínkù bá ìtànkálẹ̀ r, tí ó jẹ́ wípé Penisilini tàbí oògùn apa kòkòrò lásá lè gbọ.[14] Abẹ́rẹ́ àjẹsára fún àrùn òtútù ìta ni wọ́n ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé ó ti mú àdínkù bá ikú tí kò bá ti pa tó àwọn ènìyàn tí ó tó mílíọ́nù kan láàrín ọdún kan.
Àwọn ewu tó rọ̀ mọ
àtúnṣeGbígba abẹ́rẹ́ àjẹsára ní ìgbà èwe kò léwu nínú rárá. Bí ewu bá tilé wà, ìwọ̀nba ni yóò mọ. [6] Lára awọn eu tí ó lè ṣẹ́ yọ ni :ara gbífvóná, ìrora ojú abẹ́rẹ́ tí wọ́n fi gún oògùn náà, ati iṣan[7] ríro. Ẹ̀wé, àwọn èròjà tí wọ́n fi pèsè abẹ́rẹ́ àjẹsára lè fa ara ríro fún àwọn kọ̀ọ̀kan.
Ìpínsísọ̀rí oògùn àjẹsára
àtúnṣeAbẹ́rẹ́ àjẹsára ní àwọn ohun-àrà kan tí wọ́n wà láàyè, èyí tótikú, èyí tí kòṣiṣẹ.[8]
(a) Èyí tí kò ṣiṣẹ́
Àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára mìíràn ní àwọn ohun àrà tí kò ṣiṣẹ́ tí wọ́n fi kẹ́míkà, iná tàbí tí wọ́n sá sí Oòrùn láti lè jẹ́ kí ó kú. Àpẹrẹ irúfẹ́ àwọn abẹ́rẹ́ yí ni abẹ́rẹ àjẹsára àrùńrọpá-rọsẹ, ̀ abẹ́rẹ́ àjẹsára àrùn jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀, abẹ́rẹ́ àjẹsára àrùn dìgbòlugi àti àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára àrùn òtútù àyà.[9]
(b) Èyí tí wọ́n dín kù Àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára mìíràn ni àwọn kòkòrò alààyè tí wọ́n ti dín agbára wọn kù. Àwọn wọ̀yí ma ń jẹ́ kánká bí a bá lòó, ṣùgbọ́n ó ṣeé ṣe kí lílò wọn ó léwu fún ẹni tí ìlera mẹ́hẹ.[10]
(d) Èyí tí ó ní májèlé Àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára onímájèlé tí wọ́n ṣe láti ara àwọn májèlé tí kò ṣiṣẹ́ mọ́ tí ó sì ń fa àrùn sí àgọ́ ara dípò kí ó ṣokùnfà ìlera tó péye. (e) Ẹlẹ́yọ-kékeré Àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára tí ó bá jẹ́ ẹyọ kékeré ma ń lo àwọn légbé-n-légbé kékèké kan láti fi ṣẹ̀dá abẹ́rẹ́ àjẹsára tí ó ìmúná-dóko. (ẹ) Alásopọ̀ Àwọn kòkòrò bakitéríà kan ní èròjà "polisakaridi" tí wọ́n fi bo àwọn légbé-n-légbé kan tí wọn kò lágbé rárá láti ṣiṣẹ́ìdáàbò bo fún àwọn ọmọ ogun ara (hormone) nínú ẹ̀yà ara. (f) Àwọn àgbéyẹ̀wò Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyí, oríṣiríṣi àgbéyẹ̀wò ati iṣẹ́ ìwádí ni ó ń lọ lọ́wọ́ láti ṣe àgbékalẹ̀ àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára tuntun mìíràn tí wọn yóò ma lò káti fi kojú àìsàn tàbí àjàkálẹ̀ àrùn. Púpọ̀ nínú àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára ni wọ́n ti ṣẹ̀dá pẹ̀lú àwọn ohun-èlò tí kò ṣiṣẹ́ tàbí àwọn èyí tí wọ́n ti dín agbára wọn kù, àwọn ẹ̀yà sìntẹ́tíìkì ni wọ́n ma ń lò jùlọ láti fi ṣe abẹ́rẹ́ àjẹsára sìntẹ́tíìkì. [11]
Ìjọra oògùn àjẹsára
àtúnṣePúpọ̀ nínú àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára lè jẹ́ èy tí a ṣẹ̀dá léte àti fi kojú àìsàn kan gbòógì kan ṣoṣo, amọ́ kò ní lè ṣiṣẹ́ fún ìtọ́jú àrùn mìíràn yàtọ̀ sí àìsàn tí a ṣẹ̀dá rẹ̀ fún, àwọn ìsọ̀rí abẹ́rẹ́ àjẹsára yí ni wọ́n jẹ́ oníṣẹ́ ẹyọ kan ṣoṣo. Nígba tí àwọn irúfẹ́ abẹ́rẹ́ àjẹsára ke jì jẹ́ abẹ́rẹ́ àjẹsára gbogbo-nìṣe. Irúfẹ́ àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára yí wà fún ìtọ́jú oríṣ àrùn méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn ìsọ̀rí abẹ́rẹ́ yí ni wọ́n ń jẹ́ oníṣẹ́ púpọ̀ nígbà tí a bá fún àwọn ènìyàn.
Hẹtẹropítíìkì
àtúnṣeÀwọn irúfẹ́ abẹ́rẹ́ àjẹsára tí wọ́n wà ní ìsọ̀rí yí ni wọ́n fi ẹ̀yà ara àwọn légbé-n-légbé tí wọ́n ti kú tàbí àwọn èyí tí wọn kò lè fa àìsàn sí àgọ́ ara ènìyàn nígba tí wọ́n bá fúni.
Ìdàgba-sókè ọmọ ogun ara
àtúnṣeÀwọn ọmọ ogun ara(hormone) ma ń rí gbogbo ohun tí kò bá ti sí nínú ẹ̀jẹ̀ tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àlejò tàbí àtọ̀hún-rìn-wá, wọn sì ṣe tán láti pa wọ́n run kúrò nínú ara. Ìgbakúùgbà tí wọ́n bá ti kẹ́fín sí ìwọlé àrùn tàbí àìsàn ní inú ara, wọn yóò nti ṣe tán láti bá wọn wọ̀yá ìjà. Wọ́n ma ń gbógun ti àrùn nípasẹ̀: (1) Pípa àrùn náà ṣáájú kí ó tó inú àgọ́-ara.
(2) Ṣíṣàwárí àti dídá àwọn apá ibi cẹ́ẹ̀lì tí àrùn náà wà mọ̀ nínú ara ṣáájú kí wọ́n tó di púpọ̀.
Ọ̀nà ìtọ́jú oògùn àjẹsára Oògùn abẹ́rẹ́ àjẹsára ma ń ní àwọn ohun-èlò kan tí ó lágbára, tí ó sì ma ń jẹ́ kí wọ́n tètè ṣiṣẹ́ míá nínú àgó-ara. Ẹ̀wẹ̀, wọ́n aì le fi nkan tí kìí jẹ́ kí nkan ó bàjẹ́ sínú rẹ̀ kí ó lè wà fún ìgba pípẹ́ Àgbékalẹ̀ oògùn àjẹsára Ó tọ́ mí àwọn ìkókó, òpónló, ọmọ ọ́wọ́ àti àwọn ògo wẹẹrẹ wa ó ti bẹ̀rẹ̀ sí ń gba abẹ́rẹ́ oògùn àjẹsára láti ìgbà tí ara wọn bá ti gbó débi tí yóò ṣiṣẹ́gbe ààbò tó péye tí abẹ́rẹ́ àjẹsára fẹ́ fún wọn . nígbà tí àlékún ìdáàbò bó yóò tún mú kí àwọn ọmọ ogun ara wọn túbọ̀ jí pépé siwájú si. Àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí ni ó ń ṣokùnfà ìṣàgbékalẹ̀ gbígba a bẹ́rẹ́ àjẹsára lọ́nà tó lọ́ọ̀rìn fún àwọn ọmọdé láti ìgba èwe lóòrè-kóòrè. Àwọn oògùn abẹ́rẹ́ àjẹsára kan wà tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún àwọn ọmọ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́-orí wọn bá ṣe pọ̀ sí, bẹ́ẹ̀ kẹ̀, àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára mìíràn náà tún wà tí wọ́n yà sọ́tọ̀ tí ènìyàn lè gbà ní ẹ̀mejì tàbí jù bẹ̀ẹ́ lọ láìmọye ìgbà kí onítọ̀hún ó tó jáde láyé láti lè kojú àwọn àìsàn kan tí wọ́n sábà m ń kọlu ènìyàn bí apẹẹrẹ́: Àìsàn kòkòrò tàtánọ́ọ̀sì, àrùn rọpá-rọsẹ̀, àrùn influenza, àrùn òtútù ìta ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Bákan náà, àwọn oògùn abẹ́rẹ́ àjẹsára tí a ṣàdáyanrí rẹ̀ fún àwọn àgbalagba ni ó dá lé àwọn àìsàn bíi: àrùn influenza, àrùn òtútù àyà.
Ìtàn sókí nípa oògùn abẹ́rẹ́ àjẹsára
àtúnṣeKí wọ́n tó ṣàwárí oògùn abẹ́rẹ́ àjẹsára látarí ìbúrẹ́kẹ́ àrù cowpox àti small pox lára àwọn màlúù, ni wọ́n ti ri wípé àrùn yí ṣeé kojú nípa ṣiṣẹ́ ìyàsọ́tọ̀ àwọn kòkòrò tí ó ń fa àrùn yí, ní èyí tí wọ́n fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní nkan bí ọ̀rùndún mẹ́wàá (10th centuries) sẹ́yìn ní ilẹ̀ China. Ní ìparí ọdún 1760, Edward Jenner gbọ́ wípé àwọn òṣìṣẹ́ ilé-iṣẹ́ tí wọ́n ti ń pèsè wàra kan kò lùgbàdì àrùn smallpox nítorí wípé wọ́n ti kọ́kọ́ lùgbàdì àrùn cowpox tẹ́lẹ̀. Nígbà tí ó di ọdún 1796, ọ̀gbẹ́ni Jenner yí gbìyànjú, ó gba díẹ̀ lára ọyún ní àtẹ́lẹwẹ́̀ àwọn òṣìṣẹ́ ilé-iṣẹ́ wàrà tí wọ́n ti kó àrùn cowpox tẹ́lẹ̀ yí, ó wá gún ọmọdé kùnrin yí ní oògùn àjẹsára ti smallpox ní nkan bí ọ̀sẹ̀ mẹ́fà siwájú, lẹ́yìn èyí ó fi ọyún tí ó ti gba tí ó sì ní kòkòrò àrùn cowpox sí ara ọmọdé kùnrin ọmọ ọdún mẹ́jọ kan lásìkò àjakálé àrùn smallpox, àmọ́ ìyàlẹ́nu ibẹ̀ ni wípé ọmọdé kúnrin yí kò lùgbàdì àjàkẹ̀ àrùn lásìkò náà. Lẹ́yìn èyí, ọ̀gbẹ́ni Jenner kéde wípé oògùn àjẹsára tí òun ṣàwárí rẹ̀wípé ṣiṣẹ́ fún tọmọdé tàgba. Ìsọ̀rí oògùn abẹ́rẹ́ àjẹsára ni ọ̀gbẹ́ni Louis Pasteur ní ọdún 1880. Lẹ́yìn èyí, oríṣiríṣi abẹ́rẹ́ àjẹsára ni wọ́n tún ṣàgbékalẹ̀ tí ó sì ní àṣeyọrí rẹpẹtẹ, bíi abẹ́rẹ́ àjẹsára ti àrùn gbọ̀fungbọ̀fun, àìsàn òtútù ìta, gẹ̀gẹ̀, ati aìsàn rùbẹ́là. Àṣeyọrí ùlá gbáà ni ìṣàwárí abẹ́rẹ́ àjẹsára ati ìdàgbà-sókè tí ó níṣe pẹ̀lú àrùn rọpárọsẹ̀ tí wọ́n ń pè ní (polio) tí ó ma ń dàmú àwọn ọmọdé ní 1950 tí àrùn smaloox sì di ohun ìgbagbé ní ọdún 1960 àti 1970. Ní nkan bí ọ̀rùndún ogún (29th century), ọ̀gbẹ́ni Maurice Hilleman ni ó gbajúmọ̀ jùlọ nínú àwọn onímọ̀ tí wọ́n ṣe àwárí oògùn abẹ́rẹ́ àjẹsára. Púpọ̀ nínú iṣẹ́ ìwádí nípa lórí ìṣèwádí àti ìṣàwárí oògùn abẹ́rẹ́ àjẹsára ni ó jẹ́ wípé ó gbára lé àtìlẹyìn owó láti ọ̀dọ̀ ìjọba, ilé ẹ̀kọ́ yunifásitì, àti àwọn ilé-iṣẹ́ aládàáni tí wọn kò ní ohun ṣe pẹ́lú ìjọba. kí ó tó kè jẹ́ àṣeyọrí. Àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára kìí ṣe fún títà, ó wá fún ìlera gbogbo ènìyàn n Gbígba abẹ́rẹ́ àjẹsára gbèrú si ní ará tó kọjá. Ní àfikún, gígún abẹ́rẹ́ àjẹsára fún àwọn ẹranko ní ànfaní méjì : Àkọ́kọ́,fún ààbò àwọn ẹranko nípa àrùn àti ààbò fún àwọn ènìyàn nípa àkóràn àrùn lati ọ̀dọ̀ àwọnẹranko.[12]
Àwọn Olùdásílẹ
àtúnṣeÌforúkọsílẹ̀ àwọn olùdásílẹ̀ ni ọnà tí ìdàgba-sókẹ̀ abẹ́rẹ́ àjẹsára tún lè jẹ́ ìdènà fún ìdàgba-sókè àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára tuntun. Lára awọn ìṣòro tí ìdàgbà-sókè abẹ́rẹ́ ajẹsára tún ń kojú gẹ́gè bí ̣bí àjọ̣ elétò Ìlera Agbáyé ti sọ, ìdènà ńlá tí ó lágbára jùlọ fún ìsọ di púpọ̀ ni agbègbè orílẹ̀-èdè tí kò tíì dagbà-sókè dára dára tí wọn kò sì ní owó tí wọ́n lè fi ṣe ìdàgba-sókè oògùn abẹ́rẹ́ àjẹsára láti fi kojú àjàkálẹ̀ àrùn. [13]
Àwọn ọnà ìfijíṣẹ́
àtúnṣeRíṣiríṣi ọ̀na ni wọ́n ti là kalẹ̀ láti mú ìdàgbà-sókè bá àwọn ọnà tí a ń gba jẹ́ kí àwọn wnìyan ó ní ànfàní sí ètò ìfúni ní abẹ́rẹ́ àjẹsára lọ́nà tí ó múná-dòko. Lára àwọn ọ̀na pàtàkì tí a fi ń fi àwọn oògùn abẹ́rẹ́ àjẹsára yí jíṣẹ́ fún àwọn ènìyàn ni ìlò ìlanà ìmọ̀ ẹ̀rọ tẹkinọ́lọ́jì ti ìgbàlódé ti àtọ́lá (abẹ́rẹ́ àjẹsára tí a ń ẹ̀ sí ẹnu). Ìlana fífúni ní abẹ́rẹ́ àjẹsára sí ẹnu ma ń sisẹ́ púpò bí àwọn oníṣẹ́ ìlera tí wọ́n yọ̀nda ara wọn fún isẹ́ takun takun yí bá ti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ dára dára. Nígbà tì ìwádí lórí lílo ìlànà ìfúni ní abẹ́rẹ́ àjẹsára pẹ̀lú abẹ́rẹ́ ṣì ń lọ lọ́wọ́.
Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀
àtúnṣeOrísirísi ọ̀nà ni Ìdàgbà-sókè nípa ìwádí abẹ́rẹ́ àjẹsára tí ó n lọ lọ́wọ́, àwọn ni:
- Fún ìgbà díẹ̀ sẹ́yìn, àwọn ọmọdé nìkan ni wọ́n ń ṣe abẹ́rẹ́ àjẹsára fún, ṣùgbọ́n wọ́n ti ń ṣe fún àwọn ọ̀dọ́ àti àgbalagba láyé òde òní.
- Àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára ti ń di nkan tó wọ́pọ̀.
- Wọ́n ti ńnṣèwádí lórí àwọn ọnà tuntun tíbwọ́n ti lè ma fúní ní abẹ́rẹ́ àjẹsára.
- Won n ṣe awọn abẹrẹ ajẹsara lati mujade awon idahun ajẹsara abinibi, ati ti adaṣe.
- Wọ́n tún ń ṣe ìgbìyànjú lórí ìgbéjáde àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára to le woo aisan àwọn àrùn tó léwu.
- Wọn tún ń ṣíṣe lórí ìgbéjáde lórí àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára tó lè kojú àkọlù àwọn kòkòrò tí ń ṣekú pani.
- Àwọn onímò ìjìnlẹ̀ tún ń ṣègbìnyànjú lọ́wọ́ lọ́wọ́ láti gbé abẹ́rẹ́ àjẹsára sìntẹ́tíìkì jáde nípasẹ̀ àtúnṣe ètò àwọn kòkòrò tí ó ń fa àìsàn àti àrùn. Èyí yóò ṣe ìrÓ tó kí àwọn ògo wẹẹrẹ ó bẹ̀rẹ̀ sí ń gbaànlọ́wọ́ láti dènà bí àwọn kòkòrò wọ̀nyí ṣe ń lágbára ju àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára lọ lọ́pọ̀ ìgbà.
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "MODULE 1 – Vaccine-preventable diseases". WHO Vaccine Safety Basics. Retrieved 2020-07-11.
- ↑ "Centers for Disease Control and Prevention (CDC)". Devex. 2012-08-31. Retrieved 2020-07-11.
- ↑ "Vaccine Preventable Diseases". HealthyChildren.org. 2020-07-11. Retrieved 2020-07-11.
- ↑ "Vaccine Efficacy - an overview". ScienceDirect Topics. 2016-01-01. Retrieved 2020-07-11.
- ↑ Orenstein, W. A.; Bernier, R. H.; Dondero, T. J.; Hinman, A. R.; Marks, J. S.; Bart, K. J.; Sirotkin, B. (2020-07-11). "Field evaluation of vaccine efficacy.". Bulletin of the World Health Organization 63 (6). PMID 3879673. https://www.ncbi.nlm.nih.gov/pmc/articles/PMC2536484/. Retrieved 2020-07-11.
- ↑ "Ensuring Vaccine Safety". CDC. 2020-07-01. Retrieved 2020-07-11.
- ↑ "Leading research to understand, treat, and prevent infectious, immunologic, and allergic diseases". NIH: National Institute of Allergy and Infectious Diseases. 2020-07-08. Retrieved 2020-07-11.
- ↑ "Vaccine Types". Vaccines. Retrieved 2020-07-11.
- ↑ "Types of vaccine". Vaccine Knowledge. Retrieved 2020-07-11.
- ↑ "Different Types of Vaccines". History of Vaccines. Retrieved 2020-07-11.
- ↑ Riedel, Stefan (2001-09-11). "Edward Jenner and the history of smallpox and vaccination". Proceedings (Baylor University. Medical Center) 18 (1). doi:10.1080/08998280.2005.11928028. PMID 16200144. https://www.ncbi.nlm.nih.gov/pmc/articles/PMC1200696/. Retrieved 2020-07-11.
- ↑ "Multidisciplinary: vaccines". European Medicines Agency. 2018-09-17. Retrieved 2020-07-11.
- ↑ Belongia, Edward A.; Naleway, Allison L. (2001-09-11). "Smallpox Vaccine: The Good, the Bad, and the Ugly". Clinical Medicine and Research 1 (2). doi:10.3121/cmr.1.2.87. PMID 15931293. https://www.ncbi.nlm.nih.gov/pmc/articles/PMC1069029/. Retrieved 2020-07-11.