Oúnjẹ Kocho

Oúnjẹ ní Ethiopia

Kocho (Ge'ez: ቆጮ, ḳōč̣ō) ó jẹ́ oúnjẹ tó dà bíi búrẹ́dì èyí tí a ṣe láti ara ensete. Egbò igi ensete kún fún àwọn òun tí a gbà, tí a sì gbọ̀n dáadáa, kí á tó wá dà á papọ̀ mọ́ ìwúkàrà kí á tó fún un fún nǹkan bíi oṣù mẹ́ta sí ọdún mẹ́ta. [1] Wọ́n máa ń lò ó gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ tí ó ṣe pàtàkì nínú àwọn oúnjẹ orílẹ̀-èdè Ethiopian ní ipò tàbí pẹ̀lú injera. Ní ọdún 1975 ìdá lọ́nà ìdá mẹ́fà àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Ethiopia rọ̀gbọ̀kú pátápátá tàbí díẹ̀ lórí oúnjẹ kocho fún àwọn ìdí kan.[2] Wọ́n máa ń jẹ ẹ́ pẹ̀lú àwọn oúnjẹ bíi kitfo, gomen (ewébẹ̀ síṣè), àti ayibe. Egbò rẹ̀ jẹ́ èyí tí wọ́n máa ń gún láti yọ àwọn èyí tí ó wà nínú rẹ̀, lẹ́yìn náà ni wọ́n máa rẹ ẹ́ fún àwọn ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan kí wọ́n tó sè é. Kocho jẹ́ oúnjẹ tí wọ́n máa ń jẹ pẹ̀lú ọbẹ̀, tí ó sì jẹ́ oúnjẹ pàtàkì kan ní àwọn agbègbè kan ní orílẹ̀-èdè Ethiopia. Oúnjẹ yìí jẹ́ èyí tí ó máa ń korò bákan lẹ́nu. [3] Kocho jẹ́ nǹkan tí a le gbé pamọ́ sí abẹ́ ilẹ̀ fún oṣù mẹ́ta sí oṣù méjìlá, láti le pèsè rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ tí wọ́n le jẹ ní àsìkò ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ. Wọ́n máa ń lo Kocho gẹ́gẹ́ bí ohun èlò ìdáná fún àwọn oúnjẹ mìíràn. [4]

Kocho

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Enset: The False Banana". Atlas Obscura (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-07-21. 
  2. Keith Steinkraus Handbook of Indigenous Fermented Foods, Revised and Expanded 2018 p.260 2018 - Preview - More editions ... More than one-sixth of the Ethiopians depend completely or partially on kocho for their food (Westphal, 1975).
  3. "Catching up with Qocho". 10 June 2011. 
  4. "An Ethiopian enset feast - kocho and traditional dishes". 

5. ^ https://rippleeffect.org/blog/ethiopian-enset-feast

6. ^ https://ethiopianfood.wordpress.com/2011/06/10/catching-up-with-qocho/


Àdàkọ:Ethiopia-cuisine-stub