Oúnjẹ Shiro
Shiro, èyí tí a tún mọ̀ sí shiro wat, tàbí tsebhi shiro, ó jẹ́ ọbẹ̀ tí wọ́n máa ń fi jẹ oúnjẹ ọ̀sán àti oúnjẹ alẹ́, èyí tí a le tọpa rẹ̀ Àríwá orílẹ̀-èdè Ethiopia àti gúúsù Eritrea. Ó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára oúnjẹ orílẹ̀-èdè Eritrea àti orílẹ̀-èdè Ethiopia, ohun èlò rẹ̀ tó ṣe kókó ni chickpeas tàbí ẹ̀wà broad tí wọ́n sì máa ń sè é pẹ̀lú àlùbọ́sà, ata ilẹ̀, àti àwọn ohun èlò mìíràn. Wọ́n máa ń bu ọbẹ̀ Shiro sórí injera tàbí kitcha. Tegabino shiro jẹ́ ẹ̀yà shiro kan tí wọ́n se láti ara legume aláta rẹ́súrẹ́sú, chickpea, field pea, tàbí ẹ̀wà fava, òróró (tàbí bútà), àti omi. Wọ́n máa ń jẹ ẹ́ nínú ìsasùn kékeré pẹ̀lu sergegna injera.[2]
Shiro served upon injera is a staple food of Eritrean and Ethiopian cuisine | |||||||
Type | Stew | ||||||
---|---|---|---|---|---|---|---|
Course | |||||||
Place of origin | |||||||
Region or state | East Africa | ||||||
Main ingredients | |||||||
Variations | Shiro fit-fit | ||||||
353 kcal (1478 kJ)[1] | |||||||
| |||||||
Àdàkọ:Wikibooks-inline
|
A le se Shiro lásán, bẹ́ẹ̀ ni a le sè é mọ́ injera or taita kí á sì jẹ́ pẹ̀lú ṣíbí; èyí ni wọ́n ń ẹ̀yà rẹ̀ ní shiro fit-fit.
Shiro jẹ́ ààyò oúnjẹ nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àwọn ayẹyẹ kan bíi: Tsom (Lent), àwẹ̀ Ramadan àti àwọn àwẹ̀ mìíràn.
Bí a ṣe le sè é
àtúnṣeBí a bá fẹ́ ṣe shiro wat, ohun àkọ́kọ́ tí a máa ṣe ni láti se chickpeas tàbí lentils. Lẹ́yìn náà ni a máa yí i papọ̀ mọ́ àwọn àgbàdo kan tí a yan pẹ̀lú omi nínú abọ́ ìdáná ọ̀tọ̀ pẹ̀lú àlùbọ́sà, ata ilẹ̀, àti jíńjà.
Wò pẹ̀lú
àtúnṣeÀwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Habesha Food | Miten Shiro | purchase online".
- ↑ McCann, James C. (2009). Stirring the Pot: A History of African Cuisine. Ohio University Press. pp. 104. ISBN 9780896804647.
- Ethiopian Millennium Archived 2007-09-27 at the Wayback Machine. (electronic version, retrieved 19 June 2007)