Oríkì orúkọ àmútọ̀runwá
Orúkọ àmútọ̀runwá jẹ́ orúkọ kan tí ọmọnìyán gbé láti ọ̀run wá sí ilé ayé. Lára ọ̀nà tí àwọn Yorùbá máa gbà fún àwọn ọmọ báwọ̀nyí lórúkọ ni ọ̀nà ìyanu tí wọ́n gbà wá sí ilé ayé. [1]
Ìbejì
àtúnṣeÈjiré, ọ̀kín ará ìṣokùn,
ọba ọmọ,
yíndín Yíndín l'ójú orogún,
èji wọ̀rọ̀ lójú ìyá,
ọ̀kan n bá bí,
èjì ló wọlé tọ̀ mí wá.
èjì n bá bí ǹ bá yọ̀,
ọmọ kó ilé aláàṣẹ̀
ó sọ alákisà di onígbá áṣọ
èjìrẹ́ ọ̀kín ọmọ ẹdun n ṣ'eré orí igi.
Ìdòwú
àtúnṣeÌdòwú Ògbo.
ogbó aṣọ̀gẹ̀dẹ̀ jìà.
ẹ̀sà okùn,
Mọ̀gánná aró, abìkere létí
Èṣù lẹ́yìn ìbeji,
Ìdòwú ẹrú ibeji, ẹ̀kẹta ọmọ.
Ìgè
àtúnṣeÌgè Àdùbí,
a gbó lẹ́nu bí agogo,
ọmọ onígba irawọ̀.
bí ìyá le kú, kó kú,
bí baba le lọ, kó máa lọ ó
Elégédé ń bẹ l'óko
gbọ̀rọ̀ ń bẹ láàtàn,
ohun Ìgè Àdùbí ó jẹ, kò ni wọ́n ọn
Ìge kò rọ́jú iya,
ojú baba ló rọ́,
Ìgè ì bá rojú ìyá
kì bá kẹ́sẹ̀ síta,
ẹni bẹ Ìgè Àdùbi níṣẹ́,
ara rẹ̀ ló bẹ̀.
Òjó
àtúnṣeÒjó jèngbètièlè
Òjó ò sí nílé, ọmọ adìẹ dàgbà
Òjó tàjò dé, ọmọ adìẹ kù fénfẹ́
Òjó a jó bí ewé
Òjó tí n wẹ̀ lódò, tọ́mọge ń nawọ́ ọṣẹ.
Àjàyí
àtúnṣeÀjàyí Ògídíolú,
Òlóló, oníkànga àjípọn
Òbomi Òṣùùrù wẹdà.
Ẹkùn baba ọdẹ,
Ẹkùn pakọ̀rọ̀ wọlẹ̀.
Ẹni Ajayí gbà, gbà, gbà,
tí o le gbà tán, igúnnugún ni í gba olúwarẹ̀.
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Library, Yoruba. "Top 20 Yoruba Oriki for male and female children". An Online community for Yoruba People, Moral, Religion, Arts & Culture. Archived from the original on 2024-08-02. Retrieved 2024-08-02.