Orin Ìdárayá
Orin Ìdárayá jẹ́ orin kan tí àwọn Yorùbá máa ń kọ́ ọmọdé nígbà èwe, orin yìí a máa kún fún ọgbọ́n, òye, ìkìlọ̀, ìmọ̀ràn, ẹ̀kọ́, ìwà ọmọlúwàbí, abbl. Àwọn ọmọdé a máa kó ara jọ láti kọ orin yìí nígbà tí ọwọ́ wọn bá dilẹ̀. Ẹ jẹ́ kí á wo díẹ̀ nínú àwọn orin tí àwọn ọmọdé sáábà má ń ṣe àmúlò.
Orin ọmọdé kan
àtúnṣeọmọ kékeré kan
ń kọjá lọ́jà
ó ń wọ̀tún wòsì
bí ẹni máa fò
ẹnìkan béèrè pé
kí ló ń ṣe ọ́
tó ń wọ̀tún wòsì
bí ẹni máa fò
ẹ jẹ́ ká jọ ṣe eré
eré ayọ̀, eré ire
eré ayọ̀, ráí títì ráí ráí ràì.
Orin oge ṣíṣe
àtúnṣeMa jí ma wẹ̀ ma ṣoge
má jí ma wẹ̀ ma ṣoge
Àwẹ̀ró, èmi Akáwẹ̀ró ma wẹ̀tán
ọmọkùnrin ò leè lọ o
má jí ma wẹ̀ ma ṣoge.
Orin tó fi ìwà ọmọlúàbí hàn
àtúnṣeṣe mí l'ọ́mọ rere bí Sámúẹ́lì
ọmọ tó ń gbọ́ràn
tó ní ìtẹríba
ọmọ tí kì í bá òbí rẹ̀ jiyàn
ni kí O ṣemi Olúwa
ìwọ ńkọ́?
Ìyá ni wúrà iyebíye
tí a kò le f'owó rà
ó lóyún mi fún oṣù mẹ́sàn-án
ó pọ̀n mí f'ọ́dún mẹ́ta
ìyá ni wúrà iyebíye
tí a kò le f'owó rà.