Ọba Lájìwọwọ

(Àtúnjúwe láti Oba Lajiwowo)

Oba Lajiwowo ranse ijaya

Ọba Lájìwọwọ ránṣẹ́ ìjayà

àtúnṣe

Wọn ní ọjọ́ tí a ò bá dá ni kì í pé. Bí ilẹ̀ ti ń mọ́, tó n ṣú, bẹ́ẹ̀ ni ọjọ́ ń lọ geere bíi kẹ̀kẹ́ ológeere; bí ọ̀sùpá ti ń ràn lálaalẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ọjọ́ ń yọ́ gèèrègè bí òrí. Ọjọ́ tí Kábíèsí dá ku oṣù kan péré. Jìjì kò tí ì rí ẹni tó mọ nǹkan tó fẹ́ràn jù. Kò gbọ́ iṣẹ́ Olúwòó, bẹ́ẹ̀ ni kò rí ikọ̀ Tìmì. Síbẹ̀ náà ẹ̀rù kò bà á, àyà kò fò ó. Àfi bí akọ òkúta ni ọkàn rẹ̀ ṣele. ...

Oore ninu igbo Akilapa

Òòrẹ́ nínú igbó Akilápá

àtúnṣe

Ìlú Ògìrììyàndá jẹ́ ìlú kan tí a tẹ̀dó sí igbó ẹ̀lùjù ní ilẹ̀ ọ̀dàn. Agbára káká ni a fi ń ṣe alábàápàdé igbó jìnrìngbòdò. Àwọn pápá àti iyanrìn ni ohun kan tó pọ̀ jù níbẹ̀. Kò sí igi eléso bí ọsàn tàbí àgbálúmọ̀ rárá. Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti ọsàn wẹ́wẹ́. Ìdí rèé tí Òòrẹ́ fi kúrò ní agbègbè ìlú rẹ̀, tó fi kọrí sí agbègbè Akilápá níbi tí igbó ńlá wà. Èrò ọkàn rẹ̀ ni pé, bí òun bá tilẹ̀ débẹ̀, bóyá òún á jẹ́ bá ohun tó jọ bí ọsàn pàdé....

jiji di aya Oore

Jìjì di aya Òòrẹ́

àtúnṣe

Ní ọjọ́ tó Òòrẹ́ fẹ́ gbé ohun tí Jìjì fẹ́ràn jù fún Jìjì, gọngọ sọ lọ́jọ́ náà. Ní kùtù hàì ọjọ́ náà, láfẹ̀mọ́jú ni oníṣẹ́ ti kan ìdílé Láṣòrè lára pé ẹnìkan tún ti fi ìpinnu rẹ̀ hàn láti gbé Jìjì níyàwó pẹ̀lú ohun tí Jìjì fẹ́ràn jù. Ọ̀rọ̀ náà tilẹ̀ ti sú àwọn ará ile Jìjì pàápàá’. Wọn ò kọ́kọ́ mú un lọ́kùn-ún-kúndùn rárá. Wọ́n tún ránṣẹ́ padà pé kí onítọ̀hún dá ara rẹ̀ lójú kí ó tó máa bọ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwọn ò ní í jáde síta. Èyí táwọn ti fi àsìkò wọn ṣòfò lóró ọ̀rọ̀ Jìjì tit ó gẹ́ẹ́, alu-dùndùn kì í dárin....

jiji ati awon obi re

Jìjì àti àwọn Òbí rẹ̀

àtúnṣe

Ní ìlú Lápé-edé, ọmọbìnrin kan wá tó ń Jìjì. Adérónkẹ́ gan-an ni orúkọ àbísọ rẹ̀. Ṣùgbọ́n nítorí pé ó gbádùn láti máa kọ orin àlọ́-onítàn tó jẹ mọ́ ‘Jìjì’ tí í ṣe obìnrin inu àlọ́-onítàn yìí ni wọ́n ṣe ń pè é ní Jìjì. Orin náà lọ báyìí Jìjì aá gbọsàn, Eku lológeere, Ògìrì lọkọ ọbẹ̀, Ìrẹ̀ lẹrú wọn, Pínsínpínsín tàwọ̀sí o, Jìjì á gbọsàn. ...


Jìjì àti ẹbí Láṣòrè

àtúnṣe

Ìyá ló lọmọ ní tòótọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun tí àwọn Yorùbá máa ń sọ, ìyá lalábàárò, ìyá Jìjì tún tọ ọmọ rẹ̀ lọ pẹ̀lú ọ̀pẹ̀lọpọ̀ ẹ̀bẹ̀ àti àròyé ‘jọ̀wọ́ ọmọ mi Àṣàkẹ́. Kín lo ti ṣe ọ̀ràn ọkọ fífẹ́ yìí sí? Gbogbo àwọn ará ìlú ló ń bú wa. Àwọn ẹbí pàápàá ń sọ̀rọ̀ òdì. N ò sì bá wọn wí bí ẹní fọmọ fọ́kọ lóru. Ṣé tí ìwọ náà bá ti mú ọkùnrin kan wá, irú ọ̀rọ̀ yìí ìbá má ti wáyé. Ilé ọkọ lobìnrin í gbé, ilé ọkọ ni àdépẹ̀kun obìnrin.’...

Jìjì pako ọ̀rọ̀ sílẹ̀

àtúnṣe

Ọjọ́ tí a kò bá dá ni kì í pé, kò pẹ́, kò jìnnà tí ọjọ́ ìpàdé ẹbí Láṣòrè fi kò gẹ́gẹ́ bí ìpinnu wọn. Oníkálùkù jókòó sáyè rẹ̀. Láyọ̀ọ́nú tó jẹ́ olórí wọn náà ti bọ́ sórí àga rẹ̀. Gbogbo wọn ń tàkurọ̀ sọ, wọ́n ń retí ọmọ wọn tí wọ́n pè sí ìpàdé. Bàbá àti Ìyá Jìjì náà ti dé sí ìpàdé, àwọn náà ń wo ọ̀nà fẹ̀fẹ̀. Ohun kan ni wọ́n mọ̀ nípa Jìjì, òun náà ni pé kò jẹ́ tàpá sí ìpè ẹbí rẹ̀. Òpeni ní í ṣọlá, kì í tilẹ̀ í ṣe irú ìpè tí tẹbí-tará pè bí eléyìí lẹnìkan ò ní í dáhùn. Àfojúdi gbáà ni yóò jẹ́. Jìjì kò sì hùwà àfojúdi kan rí. Ìgbà tí Bàbá àti Ìyá rẹ̀ fẹ́ẹ́ kúró nílé ni Jìjì pàápàá ti ń múra lọ́wọ́. ...

Ọ̀rọ̀ Jìjì pèsì jẹ

àtúnṣe

Nígbà tí ọ̀rọ̀ ti rí bí eléyìí ni àwọn ẹbí Láṣòrè ti lọ fi ọ̀rọ̀ tó ọba létí. Ọba ni olórí ìlú. Òun ni bàbá olówó, òun ni bàbá tálákà; òun ni bàbá ọlọ́lá, òun ni bàbá àwọn mẹ̀kúnnù. Òun ni bàbá fọ́kùnrin; òun ni bàbá fóbìnrin. Òun kan náà ni bàbá arẹwà àti òbùrẹ́wà. Ọba ló nilẹ̀. Ìdí rèé tí àwọn ẹbí Láṣòrè ṣe fi gbogbo ọ̀rọ̀ tó Kábíèsí létí nípa ìpinnu tí Jìjì ṣe. Ṣùgbọ́n wọn ò sọ nǹkan náà tí Jìjì fẹ́ràn jù tó fẹ́ kí a fit a òun lọ́rẹ fún Kábíèsí. Ṣé ọbẹ̀ kì í mì ní ikùn àgbà, àgbà ilé sì ni Láyọ̀ọ́nú, àgbà kì í sì í ba wao jẹ́. ...

Jìjì àti Ajénifújà

àtúnṣe

Ọkùnrin kan wà ní ìlú Lápá-edé, olówó ní í ṣe. Owó ti yarọ sí i lọ́wọ́. Nítorí owó tó ní yìí ni àwọn ènìyàn ṣe máa n pè é ní Ajénifújà, alówó-lódù-bíi-ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀. Nígbà tí ìròyìn kàn án nípa ohun tí Jìjì ń fẹ́ kí ó tó lè bá ọkùnrin kan lọ, inú rẹ̀ dùn púpọ̀. Ṣé ṣaájú àsìkò yìí lòun pàápàá ti gbìyànjú, tó ti nawọ́ fífẹ́ sí Jìjì, àmọ́ tónítibi kì í ṣe bí ẹni rí i. Kò sì fún un lésì kan gúnmọ́ nígbà náà. Báyìí tí Jìjì ti lanu fọhùn pé nǹkan tóun fẹ́ràn jù, tí ẹni náà sì mú un wá; ọ̀rọ́ ti bù ṣe. Ẹmọ́ ọ̀rọ̀ náà ti lójú òpó, kí aré bẹ̀rẹ̀ ló kù ...

Jìjì àti Ọba Ìlú Àjìdò

àtúnṣe

Nígbà tí Ọba Ìlú àjìdò gbọ́ pé Ajénifújà kò rí Jìjì mú lọ sílé fi ṣe aya, ó pinnu lọ́kàn rẹ̀ pé dájúdájú ipò ọlá, ipò ẹ̀yẹ ni Jìjì fẹ́rẹ̀ jù, tó fẹ́ kí a fi fun òun. Wọ́n kúkú ti sọ pé owó fúnni kò tó ènìyàn. Bí owó ti lágbára tó, tó lókìkí tó, kò ṣeé fir a iyì àti ẹ̀yẹ. A kò lè fi wé ipò ọlá. ‘Ipò tí Jìjì sì ń fẹ́ gẹ́gẹ́ bí arẹwà obìnrin ni ipò ayaba, kí ó jẹ́ olorì àgbà pátápátá. Fáàrí àti Yànǹga rẹ̀ kúkú tó bẹ́ẹ̀ ní tòótọ́. ṣé ẹwà la á sọ pé kò ní ni? Àbí ìwà ìrẹ̀lẹ̀, ìwà tútù, ìwà ọmọlúàbí tó yẹ kí olorì Ọba ní? Dájúdájú, n ó fi ipò olorì Ọba dá a lọ́lá jọjọ....


Òòrẹ́ ní ìlú Ògìrììyàndá

àtúnṣe

Ní ìlú kan tí a ń pè ní Ògirììyàndá, Ọkùnrin kan wà níbẹ̀ tí wọ́n ń pe orúkọ rẹ̀ ní Òòrẹ́. Ìletò kan tí kò jìnnà sí Lápá-edé ni Ògìrììyàndá, fún ìdí èyí bí ènìyàn só fẹ́ẹ́ lásán, wọ́n á gbọ́ ní Ògìriìyàndá. Bí ẹnìkan sì húkọ́ lásán ní Ògìrììyàndá, gbogbo àwọn tó wa ní Ìlú Lapá-edé ló máa gbọ́ nípa rẹ̀. Gbogbo atótónù àti awuyewuye to ń lọ lórí ọ̀rọ̀ Jìjì ni àwọn ará ìlú Ògìrììyàndá mọ̀. ...

Débọ̀ Awẹ́ (2005), Jìjì Arẹwà Obìnrin Straight-Gate Publishers Limited, ISBN 978-37163-1-X, oju-iwe 1-41

Debo Awe

link title Archived 2007-08-07 at the Wayback Machine.