Ogun Àdùbí (tí àwọn èèyàn tún mọ̀ si Rògbòdìyàn Ẹ̀gbá) jẹ́ rògbòdìyàn tó wáyé nínú oṣù kẹfà sí oṣù keje ọdún 1918 ní àwọn ìlú tí ìjọba ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì ń ṣàkoso ní ilẹ̀ Nàìjíríà, nítorí àfikún owó orí to wáyé lásìkò náà. Àwọn alákòóso ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì ló gbé ètò owó orí yìí kalẹ́ àti bí wọ́n ṣe ń fipá mú àwọn èèyàn ṣiṣẹ́ lásìkò náà. Lọ́jọ́ keje oṣù kẹfà, làwọn alákòóso ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì mú àwọn àáádọ̀rin olóyè ilẹ̀ Ẹ̀gbá sátìmọ́lé, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tún fi òfin lé e pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ fa wàhálà kan, àti pé kí àwọn tó ń tako owó orí tuntun náà yọ̀nda ohun ìjà olóró tí wọn ń lò, kí wọ́n sanwó orí wọ́n, kí wọ́n má sì dìtẹ̀ aṣáájú.

Máàpù apá Ìwọ̀-ọọ̀rùn Africa, ní ọdún 1914

Ogun náà

àtúnṣe

Lọ́jọ́ kọkànlá, àwọn jagun-jagun, tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti ojú ogun ní apá ìlà-oòrùn ilẹ̀ Áfríkà, ni wọ́n pè, wá paná rògbòdìyàn ọ̀hún, kí àlááfìà lè jọba. Lọ́jọ́ kẹtàlá, oṣù kẹfá náà, àwọn ọlọ̀tẹ̀ ilẹ̀ Ẹ̀gbá fa àwọn irin tí wọ́n ṣe fún rélùwéè ní Agbesi tu nílẹ̀, wọ́n sì já ọkọ̀ ojú irin tó wà lórí eré kúrò lọ́jú ọ̀nà. Àwọn ọlọ̀tẹ̀ yóokù bá àwọn ibùdókọ̀ ọkọ̀ ojú irin to wa ni Wasinmi jẹ́, wọ́n sì tún ṣekúpa aṣojú ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì; Ọba Ọ̀ṣilẹ̀, tó jẹ́ adarí apá àríwá-ìlà-oòrùn nílẹ̀ Ẹ̀gbá, èèyàn dúdú ni Ọ̀ṣilẹ̀ yií. Fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta làwọn ọlọ̀tẹ̀ ilẹ̀ Ẹ̀gbá àti àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì fi kọjú ìjà sí ara wọn ní Otite, Tappona, Mokoloki ati Lalako ṣùgbọ́n nígbà tó di ọjọ́ kẹwàá, oṣù keje, wọ́n ti paná ìdìtẹ̀ yíi, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì mú àwọn ọlọ̀tẹ̀ kan sí àtìmọ́lé bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n pa àwọn kan nínú wọn dànù.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ogun

àtúnṣe

Àwọn eèyàn tó tó ẹgbẹ̀ta làwọn ọmọ ogun ṣekúpa, nínú wọn náà ní aṣojú ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì, Ọba Ọ̀ṣilẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀rọ̀ ilẹ̀ tó fàjà lásìkò náà ṣùgbọ́n tí kò jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ owó orí tún pẹ̀lú ohun tó fà á tí ọ̀pọ̀ eèyàn fi pàdánù ẹ̀mí wọn. Ìṣẹ̀lẹ̀ yíi ló mú kí wọ́n fagilé òmìnira ilẹ̀ Ẹ̀gbá lọ́dún 1918, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìfipámúnisìn láwọn agbègbè náà; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sí tún sọ gbígba owó orí di ọdún 1925. Àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n paná ọ̀tẹ̀ yíi ni wọ́n tún fi àmì-ẹ̀yẹ Africa General Service Medal dá lọ́lá.