Ogun Àgbẹ̀kọ̀yà

Ogun Àgbẹ́kọ̀yà ni ìjà ìfẹ̀hónú àwọn ẹgbẹ́ àwọn àgbẹ̀ tó bẹ́ sílẹ̀ lọ́dún 1968 sí 1969 nílẹ̀ Yorùbá nígbà ìṣéjọba ẹlẹ́kùnjẹkùn lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Àwọn àgbẹ̀ adáko kòkó ló ṣe agbátẹrù ìjà ìfẹ̀hónú yìí tí àwọn àgbẹ̀ yòókù sì dára pọ̀ láti tako ìṣèjọba aninilára ní àsìkò ìjọba ológun lápá iwọ̀-oòrùn Nàìjíríà.[1] [2]

Bí ìjà ìfẹ̀hónúhàn Àgbẹ́kọ̀yà ṣe bẹ́ sílẹ̀

àtúnṣe

Ogun tàbí Ìjà Àgbẹ́kọ̀yà jẹ́ ìjà ìfẹ̀hónúhàn àwọn mẹ̀kúnnùtó gbajúmọ̀ jùlọ lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà tako ìṣéjọba tó bẹ́ẹ̀ gé tí ó fi di ohun Ìtọ́kasí di òní yìí.[3] Ó jẹ́ ìjà ìfẹ̀hónúhàn láti tako ọ̀wọ́n gógó owó-orí tí àwọn ìjọba ìgbà náà ń dábáà láti bẹ̀rẹ̀ sí ní gbà lọ́wọ́ àwọn àgbẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan gbà á lérò pé ó ní ìsúnnásí òṣèlú nínú. Ìjà ìfẹ̀hónúhàn hàn yìí bẹ́ sílẹ̀ nígbà ìṣéjọba Ọ̀gágun Robert Adéyínká Adébáyọ̀, tí ó jẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ apá ìwọ̀-oòrùn Nàìjíríà.[4] [5] Ìjà yìí bẹ́ sílẹ̀ nígbà tí ìṣèjọba Ọ̀gágun Ọláyínká Adébáyọ̀ fi kún owó-orí tí àwọn àgbẹ̀ ń san fún ìjọba. Àwọn àgbẹ̀ yarí, tí wọ́n sì kọ̀ jálẹ̀ láti san ẹ̀kúnwó owó-orí yìí. Ọjọ́ burúkú èṣù gbomi mú ní lọ́jọ́ tí ìjà yìí bẹ́ sílẹ̀ lóríta abúlé Ọ̀lọ́rundá ní Ìbàdàn, olú-ìlú ìṣèjọba ìwọ-oòrùn (western region). Ìjọba ìgbà náà sọ owó-orí di dọ́là mẹ́jọ ($8), ṣùgbọ́n tí àwọn àgbẹ̀ yarí pé wọn kò lè san ju ọgbọ̀n ṣílè. Gẹ́gẹ́ bí Àlájì Lálékan Làsísì Akékaaka , ẹni tí ó jẹ́ ọ̀kan gbòógì lára àwọn tó jẹ́ olórí àwọn Àgbẹ́kọ̀yà ṣé sọ láìpẹ́ nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú ìwé ìròyìn Punch, ó ní ṣàdédé ni àwọn ọlọ́pàá ìjọba ìgbà náà ṣà dédé yìn ọn pa méjì nínú àwọn àgbẹ̀-agbinkòkó tí wọ́n péjọ sí oríta Ọlọ́rundà láti dúnàádúràá pẹ̀lú àwọn aṣojú ìjọba lórí ẹ̀kúnwó owó orí yìí. Ìṣekúpa àwọn wọ̀nyí ló mú inú bí àwọn àgbẹ̀ tí àwọn náà dojú ìjà kọ àwọn ọlọ́pàá. Ìjà yìí tàn káàkiri ilẹ̀ Yorùbá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ dúkìá ìjọba àti ẹ̀mí ló ṣòfò nígbà ìfẹ̀hónúhàn yìí. Olórí àwọn Àgbẹ́kọ̀yà nígbà náà ni Tàfá Adéoyè. Ẹgbẹ́ Àgbẹ́kọ̀yà sṣì wà títí di òní yìí.

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "How we used potent words to demobilise soldiers and their amoured tanks —Pa Olalere Ayalu, surviving leader of Agbekoya » Interview » Tribune Online". Tribune Online. 2018-02-10. Retrieved 2019-11-21. 
  2. "Agbekoya Parapo Uprising". Libertarian Socialist Wiki. 2019-08-21. Retrieved 2019-11-21. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  3. "The Agbekoya Revolt of 1968/69 • Connect Nigeria". Connect Nigeria. 2018-12-14. Archived from the original on 2021-04-19. Retrieved 2019-11-21. 
  4. Published (2015-12-15). "How a gunshot Triggered violent Agbekoya revolt –Akekaaka, Yoruba Solidarity Movement leader". Punch Newspapers. Retrieved 2019-11-21. 
  5. Gross, David M. (2015-07-03). "The Agbękoya, a Tax Revolt in Nigeria in 1968–69 • TPL". The Picket Line. Retrieved 2019-11-21.