Ògún (Ọdúnjọ)

(Àtúnjúwe láti Ogun (Odunjo))

AWỌN ÒRÌṢÀ TI YORUBA NSÌN

(1) Ògún

(2) Oríkì Ògún Onírè

(3) Ṣọ̀pọ̀nnọ́

(4) Ṣọǹgó Olúkòso

(1) Ògún

Òrìṣà ti o jẹ aláàbò fun àwọn ti o nṣe iṣẹ ogun jíjà, awọn ọlọ́dẹ, ati awọn alágbẹ̀dẹ ni Ògún; irin iṣẹ́ rẹ̀ sin i ohunkóhun ti a ba fi irin ṣe. Nitorináà, gbogbo awọn ti o ba nfi ohun ti a fi irin ṣe ṣiṣẹ wà labẹ ààbo rẹ̀ pẹlu. Fun àpẹẹrẹ, awọn ti o nfi áàké tabi ayùn gé igi; awọn gbẹ́nàgbẹ́nà ati awọn ti o nrán aṣọ; awọn ti o ti kọlà ati awọn ti o nrán awọ; awọn ti o nwa ọkọ̀ ilẹ̀, ati awọn ti o nlu irin; gbogbo awọn wọnyi gba Ògún bio aṣíwájú ati aláàbò wọn; nwọn a si maa bẹ̀ pe ki o máà jẹ ki nwọn rí ìpalára ninu iṣẹ́ wọn....

J.F. Ọdunjọ (1969), Ẹkọ Ijinlẹ Yoruba Alawiye, Fun Awọn Ile Ẹkọ Giga, Apa Keji, Longmans of Nigeria, Ojú-ìwé 88-94.