Ogun Porédaka
Ogun Porédaka (ọjọ́ kẹtàlá oṣù kọkànlá ọdún 1896) jẹ́ ìjà tí ó ṣẹlẹ̀ láàrin àwọn ogun Fránsì àti àwọn ọmọ ogun Imamate of Futa Jallon, tí àwọn ọmọ ogun Fránsì sì ségun àwọn tí ó kù lára àwọn ọmọ ogún Jallon. Lẹ́yìn ìjà yí, wọ́n fi tipátipá da Fouta Djallon mọ́ ìjọba Senegambia.
Battle of Porédaka | |||||||
---|---|---|---|---|---|---|---|
| |||||||
Àwọn agbógun tira wọn | |||||||
Imamate of Futa Jallon | France | ||||||
Àwọn apàṣẹ | |||||||
Bokar Biro | |||||||
Ìṣẹ̀lẹ̀ tó fa ìjà
àtúnṣeNí ọdún 1890 Bokar Biro ṣe ọ̀tẹ̀ lòdì sí ìjọba nípa pípa ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tí ó ó sì fi àwọn tí ó jẹ́ olóòótọ́ si sí ìjọba. Èyí fa ìjà fún ìjọba tí ó sì mú kí wọ́n lé Bokar Biro fún ìgbà díẹ̀ kí ó tó padà débẹ̀.[1] Orílẹ̀ ède Fránsì gbìyànjú láti dá sí ìjà wọn[2] ṣùgbọ́n àwọn Jallon fi ọ̀nà ẹrú bá wọn lọ̀.[3]
Ìjà
àtúnṣeNí àsìkò òjò ní ọdún 1896, orílẹ̀ èdè Fransi rán àwọn ọmọ ogun láti Senegal, Guinea àti ní Sudan, gbogbo wọn sì parapò ní Futa Jallon. Owó àwọn ọmọ ológun Fransi tẹ Timbo ní ọjọ́ kẹta oṣù kọkànlá ọdún 1896. Bokar Biro gbìyànjú láti ro àwọn olóyè láti rán lọ́wọ́ nínú lòdì sí Fransi ṣùgbọ́n akitiyan rẹ̀ já sí pàbo.
Ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kọkànlá ọdún 1896, àwọn ọmọ ogun Bokar Biro jà pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun Fransi ní Porédaka.[4] Àwọn ọmọ ogun Fransi àti Fulbe(tí arákùnrin rẹ̀, Umaru Bademba Barry jẹ́ olórí wọn) .[5] Gẹ́gẹ́ bí akéwì kan ṣe sọ, Bokar Biro kò sá lójú ogun, ṣùgbọ́n ìbon ni wọ́n fi pá.[4] Bokar Biro's son died with him.[6]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Barry 1998, p. 290-291.
- ↑ Barry 1998, p. 291.
- ↑ Klein 1998, p. 148.
- ↑ 4.0 4.1 Barry 1998, p. 293.
- ↑ O'Toole & Baker 2005, p. 23.
- ↑ Derman & Derman 1973, p. 44.