Ọkọ̀ òfurufú

(Àtúnjúwe láti Oko ofurufu)

Ọkọ̀ òfurufú jẹ ọkọ oju-ọrun ti irinṣẹ jet engine n gbe fò loju ofururu. Oko ofurufu wa ni iwon ati ipele orisirisi, on oniruuru iye (apa) ti o n gbefo loju orun. A le fi oko furufu se ise ero kiko lati ibikan si omiran, bakan naa ni awon omo ogun oju-orun ma n loo lati fi sise won [1] gbogbo àwọn bàlúù yí náà ni àwọn awakọ̀ òfurufú ma ń gbé ń fò. Àmọ́ àwọn ọkọ̀ òfurufú kékèké kan tí wọ́n ń pè ní dúróónù ni wọ́n ma ń fò lókè láì rí awakọ̀ kankan.[2] .[3]

Awon egbon ati aaburo kan ti a mo si Wright brothers ni won se awari imo ti won fi se oko ofurufu baalu akoko ti won si fi o ni odun 1903. gege bi oko ofurufu nla ti o wuwo ju afefe lo ti o si le da fo. won gbe ise won kale s'ori ise akanse ti George Caylry se lati odun 1799 nigbati o se agbekale ero baalu igbalode ti o si se awon omiran lati maa gbe awon eniyan fo lati ibikan si omiran ati ise omo ile Germany akoko ninu ise igbe eniyan fo ninu oko ofurufu Otto Lilienthal. ohun naa se ise iwadi ijinle l'ori awon oko ofurufu ti o wuwo ju afefe lo l'aarin odun 1867 ati 1896. awom igbiyanju Lilienthal lati fo ni odun 1891 ni a ri gege bii ibere fifo awon omo eniyan. Leyin igba perete ti a fi loo ninu ogun agbaye akoko (World War I), imo ijinle ninu oko ofurufu te siwaju.

Oko ofurufu ni ifesemule ti o nipon ninu awon ogun gboogi ogun agbaye keji (World War II). Oko ologun ofurufu akoko je ti omo ile Jamani ti a mo si Heinkel He 178 ni odun 1939. Won se ifilole Oko ofurufu elero pupo ni odun 1952 ti oruko re si n je de Hailland Comet. Oko ofurufu nla Boeing 707 je oko ofurufu elero pupo akoko ti o gbajugbaja ni lilo kaakiri orile agbaye. O wa ni enu ise fun odun ti o le die ni aadota, lati odun 1958 titi di odun 2013 ka fi mo ni bee.

Awon itokasi

àtúnṣe
  1. "Global air traffic hits new record" (in en-US). Channel News Asia. January 18, 2018. Archived from the original on January 3, 2021. https://web.archive.org/web/20210103124735/https://www.channelnewsasia.com/news/world/global-air-traffic-hits-new-record-9871730. 
  2. Measured in RTKs—an RTK is one tonne of revenue freight carried one kilometer.
  3. Crabtree, Tom; Hoang, Tom; Tom, Russell (2016). "World Air Cargo Forecast: 2016–2017" (PDF). Boeing Aircraft. Retrieved 2018-05-12.